2 Tẹsalonika 1:10
2 Thessalonians 1:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
ní ọjọ́ tí yóò jẹ́ ẹni tí a ó yìn lógo nínú àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ àti ẹni àwòyanu ní àárín gbogbo àwọn tí ó ti gbàgbọ́. Èyí kò yọ yín sílẹ̀, nítorí ẹ ti gba ẹ̀rí tí a jẹ́ sí yín gbọ́.
2 Thessalonians 1:10 in English
2 Thessalonians 1:10 · Berean Standard Bible
on the day He comes to be glorified in His saints and regarded with wonder by all who have believed, including you who have believed our testimony.
Context
8Òun yóò fi ìyà jẹ àwọn tí kò mọ Ọlọ́run àti àwọn tí ń ṣe àìgbọ́ràn sí ìyìnrere Jesu Olúwa wa. 9A ó fi ìparun àìnípẹ̀kun jẹ wọ́n ní yà, a ó sì ṣe wọn mọ̀ kúrò níwájú Olúwa àti inú ògo agbára rẹ̀, 10ní ọjọ́ tí yóò jẹ́ ẹni tí a ó yìn lógo nínú àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ àti ẹni àwòyanu ní àárín gbogbo àwọn tí ó ti gbàgbọ́. Èyí kò yọ yín sílẹ̀, nítorí ẹ ti gba ẹ̀rí tí a jẹ́ sí yín gbọ́. 11Nítorí èyí, àwa pẹ̀lú ń gbàdúrà fún un yín nígbà gbogbo, pé kí Ọlọ́run wa kí ó lè kà yín yẹ fún ìpè rẹ̀, àti pé nípa agbára rẹ̀, òun yóò mú gbogbo èrò rere yín ṣẹ àti gbogbo ohun tí ìgbàgbọ́ bá rú jáde. 12Wọ̀nyí ni àdúrà wa, kí orúkọ Jesu Olúwa wa lè di yíyìn lógo nínú yín àti ẹ̀yin nínú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run àti ti Jesu Kristi Olúwa.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.