2 Samuẹli 9:1
2 Samuel 9:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Dafidi sì béèrè pé, ọ̀kan nínú àwọn ẹni tí ń ṣe ìdílé Saulu kù síbẹ̀ bí? Kí èmi lè ṣe oore fún un nítorí Jonatani.
2 Samuel 9:1 in English
2 Samuel 9:1 · Berean Standard Bible
Then David asked, “Is there anyone left from the house of Saul to whom I can show kindness for the sake of Jonathan?”
Context
1Dafidi sì béèrè pé, ọ̀kan nínú àwọn ẹni tí ń ṣe ìdílé Saulu kù síbẹ̀ bí? Kí èmi lè ṣe oore fún un nítorí Jonatani. 2Ìránṣẹ́ kan sì ti wà ní ìdílé Saulu, orúkọ rẹ̀ sí ń jẹ́ Ṣiba, wọ́n sì pè é wá sọ́dọ̀ Dafidi, ọba sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ìwọ ni Ṣiba bí?”
Ó sì dáhùn wí pé, “Ìránṣẹ́ rẹ ni.” 3Ọba sì wí pé, “Kò ha sí ọ̀kan nínú ìdílé Saulu síbẹ̀, kí èmi ṣe oore Ọlọ́run fún un?”
Ṣiba sì wí fún ọba pé, “Jonatani ní ọmọ kan síbẹ̀ tó ya arọ.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.