Native Bible

2 Samuel 7:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Ǹjẹ́, Olúwa Ọlọ́run, jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà tí ìwọ sọ ní ti ìránṣẹ́ rẹ, àti ní ti ìdílé rẹ̀, kí ó dúró títí láé, kí ó sí ṣe bí ìwọ ti wí.

2 Samuel 7:25 in English

2 Samuel 7:25 · Berean Standard Bible

And now, O LORD God, confirm forever the word You have spoken concerning Your servant and his house. Do as You have promised,

Context

23Orílẹ̀-èdè kan wo ni ó sì ń bẹ ní ayé tí ó dàbí àwọn ènìyàn rẹ, àní Israẹli, àwọn tí Ọlọ́run lọ rà padà láti sọ wọ́n di ènìyàn rẹ̀, àti láti sọ wọ́n ní orúkọ, àti láti ṣe nǹkan ńlá fún un yín, àti nǹkan ìyanu fún ilé rẹ̀, níwájú àwọn ènìyàn rẹ, tí ìwọ ti rà padà fún ara rẹ láti Ejibiti wá, àní àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn òrìṣà wọn. 24Ìwọ sì fi ìdí àwọn ènìyàn rẹ, àní Israẹli kalẹ̀ fún ara rẹ láti sọ wọ́n di ènìyàn rẹ títí láé; ìwọ Olúwa sì wá di Ọlọ́run fún wọn. 25“Ǹjẹ́, Olúwa Ọlọ́run, jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà tí ìwọ sọ ní ti ìránṣẹ́ rẹ, àti ní ti ìdílé rẹ̀, kí ó dúró títí láé, kí ó sí ṣe bí ìwọ ti wí. 26Jẹ́ kí orúkọ rẹ ó ga títí láé, pé, ‘Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni Ọlọ́run lórí Israẹli!’ Sì jẹ́ kí a fi ìdílé Dafidi ìránṣẹ́ rẹ múlẹ̀ níwájú rẹ. 27“Nítorí pé ìwọ, Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli ti sọ létí ìránṣẹ́ rẹ, pé, ‘Èmí ó kọ́ ilé kan fún ọ.’ Nítorí náà ni ìránṣẹ́ rẹ sì ṣe ní i lọ́kàn rẹ̀ láti gbàdúrà yìí sí ọ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.