2 Samuẹli 7:12
2 Samuel 7:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí ọjọ́ rẹ bá pé, tí ìwọ ó sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ, èmi yóò sì gbé irú-ọmọ rẹ lékè lẹ́yìn rẹ, èyí tí ó ti inú rẹ jáde wá, èmi yóò sì fi ìdí ìjọba rẹ kalẹ̀.
2 Samuel 7:12 in English
2 Samuel 7:12 · Berean Standard Bible
And when your days are fulfilled and you rest with your fathers, I will raise up your descendant after you, who will come from your own body, and I will establish his kingdom.
Context
10Èmi ó sì yan ibìkan fún àwọn ènìyàn mi, àní Israẹli, èmi ó sì gbìn wọ́n, wọn ó sì má gbé bí ibùjókòó tiwọn, wọn kì yóò sì sípò padà mọ́; àwọn ọmọ ènìyàn búburú kì yóò sì pọ́n wọn lójúmọ́, bí ìgbà àtijọ́. 11Àti gẹ́gẹ́ bí àkókò ìgbà tí èmi ti fi àṣẹ fún àwọn onídàájọ́ lórí àwọn ènìyàn mi, àní Israẹli, èmi fi ìsinmi fún ọ lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ.
“ ‘Olúwa sì wí fún ọ pé Olúwa yóò kọ ilé kan fún ọ. 12Nígbà tí ọjọ́ rẹ bá pé, tí ìwọ ó sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ, èmi yóò sì gbé irú-ọmọ rẹ lékè lẹ́yìn rẹ, èyí tí ó ti inú rẹ jáde wá, èmi yóò sì fi ìdí ìjọba rẹ kalẹ̀. 13Òun ó sì kọ́ ilé fún orúkọ mi, èmi yóò sì fi ìdí ìjọba rẹ kalẹ̀ láéláé. 14Èmi ó máa ṣe baba fún un, òun yóò sì máa jẹ́ ọmọ mi. Bí òun bá dẹ́ṣẹ̀, èmi yóò sì fi ọ̀pá ènìyàn nà án, àti ìnà àwọn ọmọ ènìyàn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.