2 Samuẹli 6:19
2 Samuel 6:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó sì pín fún gbogbo àwọn ènìyàn náà, àní fún gbogbo ọ̀pọ̀ ènìyàn Israẹli, àti ọkùnrin àti obìnrin; fún olúkúlùkù ìṣù àkàrà kan àti ekìrí ẹran kan, àti àkàrà díndín kan. Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì túká lọ, olúkúlùkù sí ilé rẹ̀.
2 Samuel 6:19 in English
2 Samuel 6:19 · Berean Standard Bible
Then he distributed to every man and woman among the multitude of Israel a loaf of bread, a date cake,* and a raisin cake. And all the people departed, each for his own home.
Context
17Wọ́n sì mú àpótí ẹ̀rí Olúwa náà wá, wọ́n sì gbé e kalẹ̀ sípò rẹ̀ láàrín àgọ́ náà tí Dafidi pa fún un. Dafidi sì rú ẹbọ sísun àti ẹbọ ìrẹ́pọ̀ níwájú Olúwa. 18Dafidi sì parí ìṣe ẹbọ sísun àti ẹbọ ìrẹ́pọ̀ náà, ó sì súre fún àwọn ènìyàn náà ní orúkọ Olúwa àwọn ọmọ-ogun. 19Ó sì pín fún gbogbo àwọn ènìyàn náà, àní fún gbogbo ọ̀pọ̀ ènìyàn Israẹli, àti ọkùnrin àti obìnrin; fún olúkúlùkù ìṣù àkàrà kan àti ekìrí ẹran kan, àti àkàrà díndín kan. Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì túká lọ, olúkúlùkù sí ilé rẹ̀. 20Dafidi sì yípadà láti súre fún àwọn ará ilé rẹ̀, Mikali ọmọbìnrin Saulu sì jáde láti wá pàdé Dafidi, ó sì wí pé, “Báwo ni ọba Israẹli ṣe ṣe ara rẹ̀ lógo bẹ́ẹ̀ lónìí, tí ó bọ́ ara rẹ̀ sílẹ̀ lónìí lójú àwọn ìránṣẹ́bìnrin àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn lásán tí ń bọ́ra rẹ̀ sílẹ̀.” 21Dafidi sì wí fún Mikali pé, “Níwájú Olúwa ni, ẹni tí ó yàn mí fẹ́ ju baba rẹ lọ, àti ju gbogbo ìdílé rẹ lọ, láti fi èmi ṣe olórí àwọn ènìyàn Olúwa, àní lórí Israẹli, èmi ó sì súre níwájú Olúwa.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.