Native Bible

2 Samuel 3:36 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Gbogbo àwọn ènìyàn sì kíyèsi i, ó sì dára lójú wọn, gbogbo èyí tí ọba ṣe sì dára lójú gbogbo àwọn ènìyàn náà.

2 Samuel 3:36 in English

2 Samuel 3:36 · Berean Standard Bible

All the people took note and were pleased. In fact, everything the king did pleased them.

Context

34A kò sá à dè ọ́ lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni a kò kan ẹsẹ̀ rẹ ní àbà. Gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí ń ṣubú níwájú àwọn ìkà ènìyàn, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ ṣubú.” Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì tún sọkún lórí rẹ̀. 35Nígbà tí gbogbo ènìyàn sì wá láti gba Dafidi ní ìyànjú kí ó jẹun, nígbà tí ọjọ́ sì ń bẹ, Dafidi sì búra wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni kí Ọlọ́run ó ṣe sí mi àti jù bẹ́ẹ̀ lọ, bí èmi yóò bá tọ́ oúnjẹ wò, tàbí nǹkan mìíràn títí oòrùn yóò fi wọ̀!” 36Gbogbo àwọn ènìyàn sì kíyèsi i, ó sì dára lójú wọn, gbogbo èyí tí ọba ṣe sì dára lójú gbogbo àwọn ènìyàn náà. 37Gbogbo àwọn ènìyàn náà àti gbogbo Israẹli sì mọ̀ lọ́jọ́ náà pé, kì í ṣe ìfẹ́ ọba láti pa Abneri ọmọ Neri. 38Ọba sì wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ̀yin kò mọ̀ pé olórí àti ẹni ńlá kan ni ó ṣubú lónìí ní Israẹli.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.