Native Bible

2 Samuel 3:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí Joabu àti gbogbo ogun tí ó pẹ̀lú rẹ̀ sì dé, wọ́n sì sọ fún Joabu pé Abneri, ọmọ Neri ti tọ ọba wá, òun sì ti rán an lọ, ó sì ti lọ ní àlàáfíà.

2 Samuel 3:23 in English

2 Samuel 3:23 · Berean Standard Bible

When Joab and all his troops arrived, he was informed, “Abner son of Ner came to see the king, who sent him on his way in peace.”

Context

21Abneri sì wí fún Dafidi pé, “Èmi ó dìde, èmi ó sì lọ, èmi ó sì kó gbogbo Israẹli jọ sọ́dọ̀ ọba olúwa mi, wọn ó sì bá a ṣe àdéhùn, ìwọ ó sì jẹ ọba gbogbo wọn bí ọkàn rẹ ti ń fẹ́.” Dafidi sì rán Abneri lọ; òun sì lọ ní àlàáfíà. 22Sì wò ó, àwọn ìránṣẹ́ Dafidi àti Joabu sì ti ibi ìlépa ẹgbẹ́ ogun kan bọ̀, wọ́n sì mú ìkógun púpọ̀ bọ̀; ṣùgbọ́n Abneri kò sí lọ́dọ̀ Dafidi ní Hebroni; nítorí tí òun ti rán an lọ, òun sì ti lọ ní àlàáfíà. 23Nígbà tí Joabu àti gbogbo ogun tí ó pẹ̀lú rẹ̀ sì dé, wọ́n sì sọ fún Joabu pé Abneri, ọmọ Neri ti tọ ọba wá, òun sì ti rán an lọ, ó sì ti lọ ní àlàáfíà. 24Joabu sì tọ ọba wá, ó sì sọ pé, “Kí ni ìwọ ṣe yìí? Wò ó, Abneri tọ̀ ọ́ wá; èéha ti ṣe tí ìwọ sì fi rán an lọ? Òun sì ti lọ. 25Ìwọ mọ Abneri ọmọ Neri, pé ó wá láti tàn ọ́ jẹ ni, àti láti mọ ìjáde lọ rẹ, àti wíwọlé rẹ́ àti láti mọ gbogbo èyí tí ìwọ ń ṣe.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.