Native Bible

2 Samuel 24:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìbínú Olúwa sì ru sí Israẹli, ó sì ti Dafidi sí wọn, pé, “Lọ ka iye Israẹli àti Juda!”

2 Samuel 24:1 in English

2 Samuel 24:1 · Berean Standard Bible

Again the anger of the LORD burned against Israel, and He stirred up David against them, saying, “Go and take a census of Israel and Judah.”

Context

1Ìbínú Olúwa sì ru sí Israẹli, ó sì ti Dafidi sí wọn, pé, “Lọ ka iye Israẹli àti Juda!” 2Ọba sì wí fún Joabu olórí ogun, tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Lọ ní ìsinsin yìí sí gbogbo ẹ̀yà Israẹli láti Dani títí dé Beerṣeba, kí ẹ sì ka iye àwọn ènìyàn, kí èmi lè mọ iye àwọn ènìyàn náà!” 3Joabu sì wí fún ọba pé, “Kí Olúwa Ọlọ́run rẹ fi kún iye àwọn ènìyàn náà, iyekíye tí ó wù kí wọn jẹ́, ní ọ̀rọ̀ọ̀rún, ojú olúwa mi ọba yóò sì rí i, ṣùgbọ́n èétiṣe tí olúwa mi ọba fi fẹ́ nǹkan yìí?”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.