2 Samuẹli 23:21
2 Samuel 23:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó sì pa ará Ejibiti kan, ọkùnrin tí ó dára láti wò, ará Ejibiti náà sì ní ọ̀kọ̀ kan ní ọwọ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n Benaiah sì sọ̀kalẹ̀ tọ̀ ọ́ lọ, pẹ̀lú ọ̀pá ní ọwọ́, ó sì gba ọ̀kọ̀ náà lọ́wọ́ ará Ejibiti náà, ó sì fi ọ̀kọ̀ rẹ̀ pa á.
2 Samuel 23:21 in English
2 Samuel 23:21 · Berean Standard Bible
He also killed an Egyptian, a huge man. Although the Egyptian had a spear in his hand, Benaiah went against him with a club, snatched the spear from his hand, and killed the Egyptian with his own spear.
Context
19Ọlọ́lá jùlọ ni òun jẹ́ nínú àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, ó sì jẹ́ olórí fún wọn, ṣùgbọ́n òun kò tó àwọn mẹ́ta ìṣáájú. 20Benaiah, ọmọ Jehoiada, ọmọ akọni ọkùnrin kan tí Kabṣeeli, ẹni tí ó pọ̀ ní iṣẹ́ agbára, òun pa àwọn ọmọ Arieli méjì ti Moabu; ó sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú ó sì pa kìnnìún kan nínú ihò lákoko òjò-dídì. 21Ó sì pa ará Ejibiti kan, ọkùnrin tí ó dára láti wò, ará Ejibiti náà sì ní ọ̀kọ̀ kan ní ọwọ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n Benaiah sì sọ̀kalẹ̀ tọ̀ ọ́ lọ, pẹ̀lú ọ̀pá ní ọwọ́, ó sì gba ọ̀kọ̀ náà lọ́wọ́ ará Ejibiti náà, ó sì fi ọ̀kọ̀ rẹ̀ pa á. 22Nǹkan wọ̀nyí ní Benaiah ọmọ Jehoiada ṣe, ó sì ní orúkọ nínú àwọn ọkùnrin alágbára mẹ́ta náà. 23Nínú àwọn ọgbọ̀n náà, òun ní ọlá jùlọ, ṣùgbọ́n òun kò tó àwọn mẹ́ta ti ìṣáájú. Dafidi sì fi í ṣe ìgbìmọ̀ rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.