Native Bible

2 Samuel 21:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ọba sì mú àwọn ọmọkùnrin méjèèjì tí Rispa ọmọbìnrin Aiah bí fún Saulu, àní Ammoni àti Mefiboṣeti àwọn ọmọkùnrin márààrún ti Merabu, ọmọbìnrin Saulu, àwọn tí ó bí fún Adrieli ọmọ Barsillai ará Mehola.

2 Samuel 21:8 in English

2 Samuel 21:8 · Berean Standard Bible

But the king took Armoni and Mephibosheth, the two sons whom Rizpah daughter of Aiah had borne to Saul, as well as the five sons whom Merab * daughter of Saul had borne to Adriel son of Barzillai the Meholathite.

Context

6Mú ọkùnrin méje nínú àwọn ọmọ rẹ̀ fún wá, àwa ó sì so wọ́n rọ̀ fún Olúwa ní Gibeah ti Saulu ẹni tí Olúwa ti yàn.” Ọba sì wí pé, “Èmi ó fi wọ́n fún yín.” 7Ṣùgbọ́n ọba dá Mefiboṣeti sí, ọmọ Jonatani, ọmọ Saulu, nítorí ìbúra Olúwa tí ó wà láàrín Dafidi àti Jonatani ọmọ Saulu. 8Ọba sì mú àwọn ọmọkùnrin méjèèjì tí Rispa ọmọbìnrin Aiah bí fún Saulu, àní Ammoni àti Mefiboṣeti àwọn ọmọkùnrin márààrún ti Merabu, ọmọbìnrin Saulu, àwọn tí ó bí fún Adrieli ọmọ Barsillai ará Mehola. 9Ó sì fi wọ́n lé àwọn ará Gibeah lọ́wọ́, wọ́n sì so wọ́n rọ̀ lórí òkè níwájú Olúwa: àwọn méjèèjì sì ṣubú lẹ́ẹ̀kan, a sì pa wọ́n ní ìgbà ìkórè, ní ìbẹ̀rẹ̀, ìkórè ọkà barle. 10Rispa ọmọbìnrin Aiah sì mú aṣọ ọ̀fọ̀ kan, ó sì tẹ́ fún ará rẹ̀ lórí àpáta ní ìbẹ̀rẹ̀ ìkórè, títí omi fi dà sí wọn lára láti ọ̀run wá, kò sì jẹ́ kí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run bà lé wọn lọ́sàn, tàbí àwọn ẹranko igbó lóru.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.