Native Bible

2 Samuel 20:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ọba sì wí fún Amasa pé, “Pe àwọn ọkùnrin Juda fún mi ní ìwọ̀n ọjọ́ mẹ́ta òní, kí ìwọ náà kí o sì wà níhìn-ín yìí.”

2 Samuel 20:4 in English

2 Samuel 20:4 · Berean Standard Bible

Then the king said to Amasa, “Summon the men of Judah to come to me within three days, and be here yourself.”

Context

2Gbogbo àwọn ọkùnrin Israẹli sì lọ kúrò lẹ́yìn Dafidi, wọ́n sì ń tọ́ Ṣeba ọmọ Bikri lẹ́yìn, ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin Juda sì fi ara mọ́ ọba wọn láti odò Jordani wá títí ó fi dé Jerusalẹmu. 3Dafidi sì wà ní ilé rẹ̀ ní Jerusalẹmu; ọba sì mú àwọn obìnrin mẹ́wàá tí í ṣe àlè rẹ̀, àwọn tí ó ti fi sílẹ̀ láti máa ṣọ́ ilé, Ó sì há wọn mọ́ ilé, ó sì ń bọ́ wọn, ṣùgbọ́n kò sì tún wọlé tọ̀ wọ́n mọ́. A sì sé wọn mọ́ títí di ọjọ́ ikú wọn, wọ́n sì wà bí opó. 4Ọba sì wí fún Amasa pé, “Pe àwọn ọkùnrin Juda fún mi ní ìwọ̀n ọjọ́ mẹ́ta òní, kí ìwọ náà kí o sì wà níhìn-ín yìí.” 5Amasa sì lọ láti pe àwọn ọkùnrin Juda; ṣùgbọ́n ó sì dúró pẹ́ ju àkókò tí a fi fún un. 6Dafidi sì wí fún Abiṣai pé, “Nísinsin yìí Ṣeba ọmọ Bikri yóò ṣe wá ní ibi ju ti Absalomu lọ; ìwọ mú àwọn ìránṣẹ́ olúwa rẹ, kí o sì lépa rẹ̀, kí ó má ba à rí ìlú olódi wọ̀, kí ó sì bọ́ lọ́wọ́ wa.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.