Native Bible

2 Samuel 20:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Obìnrin ọlọ́gbọ́n kan sì kígbe sókè láti ìlú náà wá pé, “Fetísílẹ̀! Fetísílẹ̀! Èmi bẹ̀ yín, ẹ sọ fún Joabu pé, ‘Súnmọ́ ìhín yìí èmi ó sì bá a sọ̀rọ̀.’ ”

2 Samuel 20:16 in English

2 Samuel 20:16 · Berean Standard Bible

a wise woman called out from the city, “Listen! Listen! Please tell Joab to come here so that I may speak with him.”

Context

14Ṣeba kọjá nínú gbogbo ẹ̀yà Israẹli sí Abeli-Beti-Maaka, àti gbogbo àwọn ará Beri; wọ́n sì kó ara wọn jọ, wọ́n sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn pẹ̀lú. 15Wọ́n wá, wọ́n sì dó tì Ṣeba ní Abeli-Beti-Maaka, wọ́n sì mọ odi ti ìlú náà, odi náà sì dúró ti odi ìlú náà, gbogbo ènìyàn tí ń bẹ lọ́dọ̀ Joabu sì ń gbìyànjú láti wó ògiri náà lulẹ̀. 16Obìnrin ọlọ́gbọ́n kan sì kígbe sókè láti ìlú náà wá pé, “Fetísílẹ̀! Fetísílẹ̀! Èmi bẹ̀ yín, ẹ sọ fún Joabu pé, ‘Súnmọ́ ìhín yìí èmi ó sì bá a sọ̀rọ̀.’ ” 17Nígbà tí òun sì súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀, obìnrin náà sì wí pé, “Ìwọ ni Joabu bí?” Òun sì dáhùn wí pé, “Èmi náà ni.” Obìnrin náà sì wí fún un pé, “Gbọ́ ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́bìnrin rẹ.” Òun sì dáhùn wí pé, “Èmi ń gbọ́.” 18Ó sì sọ̀rọ̀ wí pé, “Wọ́n ti ń wí ṣáájú pé, ‘Gba ìdáhùn rẹ ní Abeli,’ bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì parí ọ̀ràn náà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.