Native Bible

2 Samuel 2:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Dafidi rán oníṣẹ́ sí àwọn ọkùnrin Jabesi Gileadi láti sọ fún wọn pé, “Olúwa bùkún un yín fún fífi inú rere yín hàn sí Saulu ọ̀gá yín nípa sí sin ín.

2 Samuel 2:5 in English

2 Samuel 2:5 · Berean Standard Bible

So David sent messengers to the men of Jabesh-gilead to tell them, “The LORD bless you, because you showed this kindness to Saul your lord when you buried him.

Context

3Dafidi sì mú àwọn ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, olúkúlùkù pẹ̀lú ìdílé rẹ̀, wọ́n sì ń gbé ní Hebroni àti ìlú rẹ̀ mìíràn. 4Nígbà náà àwọn ọkùnrin ará Juda wá sí Hebroni, níbẹ̀ ni wọ́n ti fi àmì òróró yan Dafidi gẹ́gẹ́ bí ọba lórí ilé Juda. Nígbà tí wọ́n sọ fún Dafidi pé, àwọn ọkùnrin ti Jabesi Gileadi ni ó sin òkú Saulu, 5Dafidi rán oníṣẹ́ sí àwọn ọkùnrin Jabesi Gileadi láti sọ fún wọn pé, “Olúwa bùkún un yín fún fífi inú rere yín hàn sí Saulu ọ̀gá yín nípa sí sin ín. 6Kí Olúwa kí ó fi inú rere àti òtítọ́ fún un yín, èmi náà yóò sì san oore yìí fún un yín, nítorí tí ẹ̀yin ti ṣe èyí. 7Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ẹ mú ara yín le, kí ẹ sì ní ìgboyà, nítorí Saulu ọba yín ti kú, ilé Juda sì ti fi àmì òróró yàn mí ní ọba lórí wọn.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.