2 Samuẹli 2:25
2 Samuel 2:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn ọmọ Benjamini sì kó ara wọn jọ wọ́n tẹ̀lé Abneri, wọ́n sì wá di ẹgbẹ́ kan, wọ́n sì dúró lórí òkè kan.
2 Samuel 2:25 in English
2 Samuel 2:25 · Berean Standard Bible
The Benjamites rallied to Abner, formed a single unit, and took their stand atop a hill.
Context
23Ṣùgbọ́n ó sí kọ̀ láti padà, Abneri sì fi òdì ọ̀kọ̀ gún un lábẹ́ inú, ọ̀kọ̀ náà sì jáde ní ẹ̀yìn rẹ̀: òun sì ṣubú lulẹ̀ níbẹ̀, ó sì kú ní ibi kan náà; ó sí ṣe gbogbo ènìyàn tí ó dé ibi tí Asaheli gbé ṣubú si, tí ó sì kú, sì dúró jẹ́. 24Joabu àti Abiṣai sì lépa Abneri: oòrùn sì wọ̀, wọ́n sì dé òkè ti Amima tí o wà níwájú Giah lọ́nà ijù Gibeoni. 25Àwọn ọmọ Benjamini sì kó ara wọn jọ wọ́n tẹ̀lé Abneri, wọ́n sì wá di ẹgbẹ́ kan, wọ́n sì dúró lórí òkè kan. 26Abneri sì pe Joabu, ó sì bi í léèrè pé, “Idà yóò máa parun títí láéláé bí? Ǹjẹ́ ìwọ kò ì tí ì mọ̀ pé yóò korò níkẹyìn? Ǹjẹ́ yóò ha ti pẹ́ tó kí ìwọ tó sọ fún àwọn ènìyàn náà, kí wọ́n dẹ́kun láti máa lépa arákùnrin wọn.” 27Joabu sì wí pé, “Bí Ọlọ́run ti ń bẹ, bí kò ṣe bí ìwọ ti wí, nítòótọ́ ní òwúrọ̀ ni àwọn ènìyàn náà ìbá padà lẹ́yìn arákùnrin wọn.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.