2 Samuẹli 2:12
2 Samuel 2:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Abneri ọmọ Neri pẹ̀lú àwọn ọkùnrin ti Iṣboṣeti ọmọkùnrin Saulu kúrò ní Mahanaimu, wọ́n sì lọ sí Gibeoni.
2 Samuel 2:12 in English
2 Samuel 2:12 · Berean Standard Bible
One day Abner son of Ner and the servants of Ish-bosheth son of Saul marched out from Mahanaim to Gibeon.
Context
10Iṣboṣeti ọmọ Saulu sì jẹ́ ọmọ ogójì ọdún nígbà tí ó jẹ ọba lórí Israẹli, ó sì jẹ ọba fún ọdún méjì. Ilé Juda sì ń tọ Dafidi lẹ́yìn. 11Gbogbo àkókò tí Dafidi fi jẹ ọba ní Hebroni lórí ilé Juda sì jẹ́ ọdún méje àti oṣù mẹ́fà. 12Abneri ọmọ Neri pẹ̀lú àwọn ọkùnrin ti Iṣboṣeti ọmọkùnrin Saulu kúrò ní Mahanaimu, wọ́n sì lọ sí Gibeoni. 13Joabu ọmọ Seruiah pẹ̀lú àwọn ọkùnrin Dafidi jáde lọ láti lọ bá wọn ní adágún Gibeoni. Ẹgbẹ́ kan sì jókòó ní apá kan adágún, àti ẹgbẹ́ kejì ní apá kejì adágún. 14Nígbà náà, Abneri sọ fún Joabu pé, “Jẹ́ kí díẹ̀ nínú àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yìí ó dìde láti bá ara wọn jà níwájú wa.”
Joabu sì dáhùn pé, “Ó dára, jẹ́ kí wọ́n ṣe é.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.