Native Bible

2 Samuel 2:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Lẹ́yìn àkókò yìí, Dafidi wádìí lọ́wọ́ Olúwa. Ó sì béèrè pé, “Ṣé èmi lè gòkè lọ sí ọ̀kan lára àwọn ìlú Juda?” Olúwa sì wí pé, “Gòkè lọ.” Dafidi sì béèrè pé, “Ní ibo ni kí èmi kí ó lọ?” Olúwa sì dá a lóhùn pé, “Sí Hebroni.”

2 Samuel 2:1 in English

2 Samuel 2:1 · Berean Standard Bible

Some time later, David inquired of the LORD, “Should I go up to one of the towns of Judah?” “Go up,” the LORD answered. Then David asked, “Where should I go?” “To Hebron,” replied the LORD.

Context

1Lẹ́yìn àkókò yìí, Dafidi wádìí lọ́wọ́ Olúwa. Ó sì béèrè pé, “Ṣé èmi lè gòkè lọ sí ọ̀kan lára àwọn ìlú Juda?” Olúwa sì wí pé, “Gòkè lọ.” Dafidi sì béèrè pé, “Ní ibo ni kí èmi kí ó lọ?” Olúwa sì dá a lóhùn pé, “Sí Hebroni.” 2Nígbà náà ni Dafidi gòkè lọ síbẹ̀ pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀ méjì Ahinoamu ará Jesreeli, àti Abigaili obìnrin opó Nabali ti Karmeli. 3Dafidi sì mú àwọn ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, olúkúlùkù pẹ̀lú ìdílé rẹ̀, wọ́n sì ń gbé ní Hebroni àti ìlú rẹ̀ mìíràn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.