2 Samuẹli 19:8
2 Samuel 19:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọba sì dìde, ó sì jókòó ní ẹnu-ọ̀nà, wọ́n sì wí fún gbogbo àwọn ènìyàn náà pé, “Wò ó, ọba jókòó ní ẹnu-ọ̀nà.” Gbogbo ènìyàn sì wá sí iwájú ọba. Nítorí pé, Israẹli ti sá, olúkúlùkù sí àgọ́ rẹ̀.
2 Samuel 19:8 in English
2 Samuel 19:8 · Berean Standard Bible
So the king got up and sat in the gate, and all the people were told: “Behold, the king is sitting in the gate.” So they all came before the king. Meanwhile, the Israelites had fled, each man to his home.
Context
6Nítorí pé ìwọ fẹ́ àwọn ọ̀tá rẹ, ìwọ sì kórìíra àwọn ọ̀rẹ́ rẹ. Nítorí tí ìwọ wí lónìí pé, Ìwọ kò náání àwọn ọmọ ọba tàbí àwọn ìránṣẹ́; èmi sì rí lónìí pé, ìbá ṣe pé Absalomu wà láààyè, kí gbogbo wa sì kú lónìí, ǹjẹ́ ìbá dùn mọ́ ọ gidigidi. 7Sì dìde nísinsin yìí, lọ, kí o sì sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ, nítorí pé èmi fi Olúwa búra, bí ìwọ kò bá lọ, ẹnìkan kì yóò bá ọ dúró ni alẹ́ yìí, èyí ni yóò sì burú fún ọ ju gbogbo ibi tí ojú rẹ ti ń rí láti ìgbà èwe rẹ wá títí ó fi di ìsinsin yìí.” 8Ọba sì dìde, ó sì jókòó ní ẹnu-ọ̀nà, wọ́n sì wí fún gbogbo àwọn ènìyàn náà pé, “Wò ó, ọba jókòó ní ẹnu-ọ̀nà.” Gbogbo ènìyàn sì wá sí iwájú ọba.
Nítorí pé, Israẹli ti sá, olúkúlùkù sí àgọ́ rẹ̀. 9Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì ń bà ara wọn jà nínú gbogbo ẹ̀yà Israẹli, pé, “Ọba ti gbà wá là lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa, ó sì ti gbà wá kúrò lọ́wọ́ àwọn Filistini; òun sì wá sá kúrò ní ìlú nítorí Absalomu. 10Absalomu, tí àwa fi jẹ ọba lórí wa sì kú ní ogun, ǹjẹ́ èéṣe tí ẹ̀yin fi dákẹ́ tí ẹ̀yin kò sì sọ̀rọ̀ kan láti mú ọba padà wá?”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.