2 Samuẹli 19:4
2 Samuel 19:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọba sì bo ojú rẹ̀, ọba sì kígbe ní ohùn rara pé, “Á à! Ọmọ mi Absalomu! Absalomu ọmọ mi, ọmọ mi!”
2 Samuel 19:4 in English
2 Samuel 19:4 · Berean Standard Bible
But the king covered his face and cried out at the top of his voice, “O my son Absalom! O Absalom, my son, my son!”
Context
2Ìṣẹ́gun ọjọ́ náà sì di àwẹ̀ fún gbogbo àwọn ènìyàn náà, nítorí àwọn ènìyàn náà gbọ́ ní ọjọ́ náà bí inú ọba ti bàjẹ́ nítorí ọmọ rẹ̀. 3Àwọn ènìyàn náà sì yọ́ lọ sí ìlú ní ọjọ́ náà gẹ́gẹ́ bí àwọn bí ènìyàn tí a dójútì ṣe máa ń yọ́ lọ nígbà tí wọ́n bá sá lójú ìjà. 4Ọba sì bo ojú rẹ̀, ọba sì kígbe ní ohùn rara pé, “Á à! Ọmọ mi Absalomu! Absalomu ọmọ mi, ọmọ mi!” 5Joabu sì wọ inú ilé tọ ọba lọ, ó sì wí pé, “Ìwọ dójúti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ lónìí, àwọn tí ó gba ẹ̀mí rẹ̀ là lónìí, àti ẹ̀mí àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, àti ti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀, àti àwọn aya rẹ̀, àti ẹ̀mí àwọn obìnrin rẹ. 6Nítorí pé ìwọ fẹ́ àwọn ọ̀tá rẹ, ìwọ sì kórìíra àwọn ọ̀rẹ́ rẹ. Nítorí tí ìwọ wí lónìí pé, Ìwọ kò náání àwọn ọmọ ọba tàbí àwọn ìránṣẹ́; èmi sì rí lónìí pé, ìbá ṣe pé Absalomu wà láààyè, kí gbogbo wa sì kú lónìí, ǹjẹ́ ìbá dùn mọ́ ọ gidigidi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.