2 Samuẹli 19:11
2 Samuel 19:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Dafidi ọba sì ránṣẹ́ sí Sadoku, àti sí Abiatari àwọn àlùfáà pé, “Sọ fún àwọn àgbàgbà Juda, pé, ‘Èéṣe tí ẹ̀yin fi kẹ́yìn láti mú ọba padà wá sí ilé rẹ̀? Ọ̀rọ̀ gbogbo Israẹli sì ti dé ọ̀dọ̀ ọba àní ní ilé rẹ̀.
2 Samuel 19:11 in English
2 Samuel 19:11 · Berean Standard Bible
Then King David sent this message to Zadok and Abiathar, the priests: “Say to the elders of Judah, ‘Why should you be the last to restore the king to his palace, since the talk of all Israel has reached the king at his quarters?
Context
9Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì ń bà ara wọn jà nínú gbogbo ẹ̀yà Israẹli, pé, “Ọba ti gbà wá là lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa, ó sì ti gbà wá kúrò lọ́wọ́ àwọn Filistini; òun sì wá sá kúrò ní ìlú nítorí Absalomu. 10Absalomu, tí àwa fi jẹ ọba lórí wa sì kú ní ogun, ǹjẹ́ èéṣe tí ẹ̀yin fi dákẹ́ tí ẹ̀yin kò sì sọ̀rọ̀ kan láti mú ọba padà wá?” 11Dafidi ọba sì ránṣẹ́ sí Sadoku, àti sí Abiatari àwọn àlùfáà pé, “Sọ fún àwọn àgbàgbà Juda, pé, ‘Èéṣe tí ẹ̀yin fi kẹ́yìn láti mú ọba padà wá sí ilé rẹ̀? Ọ̀rọ̀ gbogbo Israẹli sì ti dé ọ̀dọ̀ ọba àní ní ilé rẹ̀. 12Ẹ̀yin ni ara mi, ẹ̀yin ni egungun mi, àti ẹran-ara mi: èéṣì ti ṣe tí ẹ̀yin fi kẹ́yìn láti mú ọba padà wá.’ 13Kí ẹ̀yin sì wí fún Amasa pé, ‘Egungun àti ẹran-ara mi kọ́ ni ìwọ jẹ́ bí? Kí Ọlọ́run ó ṣe bẹ́ẹ̀ sí mi àti jù bẹ́ẹ̀ lọ pẹ̀lú, bí ìwọ kò ba ṣe olórí ogun níwájú mi títí, ní ipò Joabu.’ ”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.