2 Samuẹli 18:32
2 Samuel 18:32 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọba sì bi Kuṣi pé, “Àlàáfíà kọ́ Absalomu ọ̀dọ́mọdékùnrin náà wá bí?” Kuṣi sì dáhùn pe, “Kí àwọn ọ̀tá olúwa mi ọba, àti gbogbo àwọn tí ó dìde sí ọ ní ibi, rí bí ọ̀dọ́mọdékùnrin náà.”
2 Samuel 18:32 in English
2 Samuel 18:32 · Berean Standard Bible
The king asked the Cushite, “Is the young man Absalom all right?” And the Cushite replied, “May what has become of the young man happen to the enemies of my lord the king and to all who rise up against you to harm you.”
Context
30Ọba sì wí fún un pé, “Yípadà kí o sì dúró níhìn-ín.” Òun sì yípadà, ó sì dúró jẹ́ẹ́. 31Sì wò ó, Kuṣi sì wí pé, “Ìyìnrere fún olúwa mi ọba, nítorí tí Olúwa ti gbẹ̀san rẹ lónìí lára gbogbo àwọn tí ó dìde sí ọ.” 32Ọba sì bi Kuṣi pé, “Àlàáfíà kọ́ Absalomu ọ̀dọ́mọdékùnrin náà wá bí?”
Kuṣi sì dáhùn pe, “Kí àwọn ọ̀tá olúwa mi ọba, àti gbogbo àwọn tí ó dìde sí ọ ní ibi, rí bí ọ̀dọ́mọdékùnrin náà.” 33Ọba sì kẹ́dùn púpọ̀ ó sì gòkè lọ, sí yàrá tí ó wà lórí òkè ibodè, ó sì sọkún; báyìí ni ó sì ń wí bí ó ti ń lọ, “Ọmọ mi Absalomu! Ọmọ mi, ọmọ mí Absalomu! Á à! Ìbá ṣe pé èmi ni ó kú ní ipò rẹ̀! Absalomu ọmọ mi, ọmọ mi!”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.