Native Bible

2 Samuel 18:28 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ahimasi sì dé, ó sì wí fún ọba pé, “Àlàáfíà!” Ó sì wólẹ̀ fún ọba, ó dojúbolẹ̀ ó sì wí pé, “Alábùkún fún ni Olúwa Ọlọ́run rẹ, ẹni tí ó fi àwọn ọkùnrin tí ó gbé ọwọ́ wọn sókè sí olúwa mi ọba lé ọ lọ́wọ́.”

2 Samuel 18:28 in English

2 Samuel 18:28 · Berean Standard Bible

Then Ahimaaz called out to the king, “All is well!” And he bowed facedown before the king. He continued, “Blessed be the LORD your God! He has delivered up the men who raised their hands against my lord the king.”

Context

26Alóre náà sì rí ọkùnrin mìíràn tí ń sáré, alóre sì kọ sí ẹni tí ń ṣọ́ bodè, ó sì wí pe, “Wò ó, ọkùnrin kan ń sáré òun nìkan.” Ọba sì wí pé, “Èyí náà pẹ̀lú ń mú ìròyìn rere wá.” 27Alóre náà sì wí pé, “Èmi wo ìsáré ẹni tí ó wà níwájú ó dàbí ìsáré Ahimasi ọmọ Sadoku.” Ọba sì wí pé, “Ènìyàn re ni, ó sì ń mú ìyìnrere wá!” 28Ahimasi sì dé, ó sì wí fún ọba pé, “Àlàáfíà!” Ó sì wólẹ̀ fún ọba, ó dojúbolẹ̀ ó sì wí pé, “Alábùkún fún ni Olúwa Ọlọ́run rẹ, ẹni tí ó fi àwọn ọkùnrin tí ó gbé ọwọ́ wọn sókè sí olúwa mi ọba lé ọ lọ́wọ́.” 29Ọba sì béèrè pé, “Àlàáfíà ha wà fún Absalomu, ọmọdékùnrin náà bí?” Ahimasi sì dáhùn pé, “Nígbà tí Joabu rán ìránṣẹ́ ọba, àti èmi ìránṣẹ́ rẹ̀, mo rí ọ̀pọ̀ ènìyàn, ṣùgbọ́n èmi kò mọ ìdí rẹ̀.” 30Ọba sì wí fún un pé, “Yípadà kí o sì dúró níhìn-ín.” Òun sì yípadà, ó sì dúró jẹ́ẹ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.