2 Samuẹli 18:19
2 Samuel 18:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ahimasi ọmọ Sadoku sì wí pé, “Jẹ́ kí èmi ó súré nísinsin yìí, kí èmi sì mú ìròyìn tọ ọba lọ, bí Olúwa ti gbẹ̀san rẹ̀ lára àwọn ọ̀tá rẹ̀.”
2 Samuel 18:19 in English
2 Samuel 18:19 · Berean Standard Bible
Then Ahimaaz son of Zadok said, “Please let me run and tell the king the good news that the LORD has avenged him of his enemies.”
Context
17Wọ́n sì gbé Absalomu, wọ́n sì sọ ọ́ sínú ihò ńlá kan ní igbó náà, wọ́n sì kó òkúta púpọ̀ jọ sí i lórí, gbogbo Israẹli sì sá, olúkúlùkù sí inú àgọ́ rẹ̀. 18Absalomu ní ìgbà ayé rẹ̀, sì mọ ọ̀wọ́n kan fún ara rẹ̀, tí ń bẹ ní àfonífojì Ọba: nítorí tí ó wí pé, “Èmi kò ní ọmọkùnrin tí yóò pa orúkọ mi mọ́ ní ìrántí,” òun sì pe ọ̀wọ́n náà nípa orúkọ rẹ̀, a sì ń pè é títí di òní, ní ọ̀wọ́n Absalomu. 19Ahimasi ọmọ Sadoku sì wí pé, “Jẹ́ kí èmi ó súré nísinsin yìí, kí èmi sì mú ìròyìn tọ ọba lọ, bí Olúwa ti gbẹ̀san rẹ̀ lára àwọn ọ̀tá rẹ̀.” 20Joabu sì wí fún un pé, “Ìwọ kì yóò mù ìròyìn lọ lónìí, ṣùgbọ́n ìwọ ó mú lọ ní ọjọ́ mìíràn, ṣùgbọ́n lónìí yìí ìwọ kì yóò mú ìròyìn kan lọ, nítorí tí ọmọ ọba ṣe aláìsí.” 21Joabu sì wí fún Kuṣi pé, “Lọ, kí ìwọ ro ohun tí ìwọ rí fún ọba.” Kuṣi sì wólẹ̀ fún Joabu ó sì sáré.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.