2 Samuẹli 17:5
2 Samuel 17:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Absalomu sì wí pé, “Ǹjẹ́ pe Huṣai ará Arki, àwa ó sì gbọ́ èyí tí ó wà lẹ́nu rẹ̀ pẹ̀lú.”
2 Samuel 17:5 in English
2 Samuel 17:5 · Berean Standard Bible
Then Absalom said, “Summon Hushai the Archite as well, and let us hear what he too has to say.”
Context
3Èmi ó sì mú gbogbo àwọn ènìyàn padà sọ́dọ̀ rẹ bi ìgbà tí ìyàwó bá padà sí ọ̀dọ̀ ọkọ rẹ̀. Ọkàn ẹnìkan ṣoṣo tí ìwọ ń wá yìí ni ó túmọ̀ sí ìpadàbọ̀ gbogbo wọn; gbogbo àwọn ènìyàn yóò sì wà ní àlàáfíà.” 4Ọ̀rọ̀ náà sì tọ́ lójú Absalomu, àti lójú gbogbo àwọn àgbàgbà Israẹli. 5Absalomu sì wí pé, “Ǹjẹ́ pe Huṣai ará Arki, àwa ó sì gbọ́ èyí tí ó wà lẹ́nu rẹ̀ pẹ̀lú.” 6Huṣai sì dé ọ̀dọ̀ Absalomu, Absalomu sì wí fún un pé, “Báyìí ni Ahitofeli wí, kí àwa ṣe bí ọ̀rọ̀ rẹ bí? Bí ko bá sì tọ́ bẹ́ẹ̀, ìwọ wí.” 7Huṣai sì wí fún Absalomu pé, “Ìmọ̀ tí Ahitofeli gbà yìí, kò dára nísinsin yìí.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.