2 Samuẹli 17:11
2 Samuel 17:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Nítorí náà èmi dámọ̀ràn pé, kí gbogbo Israẹli wọ́jọ pọ̀ sọ́dọ̀ rẹ, láti Dani títí dé Beerṣeba, gẹ́gẹ́ bí iyanrìn létí òkun fún ọ̀pọ̀lọpọ̀; àti pé, kí ìwọ tìkára rẹ̀ ó lọ sí ogun náà.
2 Samuel 17:11 in English
2 Samuel 17:11 · Berean Standard Bible
Instead, I advise that all Israel from Dan to Beersheba—a multitude like the sand on the seashore—be gathered to you, and that you yourself lead them into battle.
Context
9Kíyèsi i, ó ti fi ara rẹ̀ pamọ́ nísinsin yìí ni ihò kan, tàbí ní ibòmíràn: yóò sì ṣe, nígbà tí díẹ̀ nínú wọn bá kọ́ ṣubú, ẹnikẹ́ni tí ó bá gbọ́ yóò sì wí pé, ‘Ìparun sì ń bẹ́ nínú àwọn ènìyàn tí ń tọ Absalomu lẹ́yìn.’ 10Ẹni tí ó sì ṣe alágbára, tí ọkàn rẹ̀ sì dàbí ọkàn kìnnìún, yóò sì rẹ̀ ẹ́: nítorí gbogbo Israẹli ti mọ̀ pé alágbára ni baba rẹ, àti pé, àwọn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ jẹ́ alágbára. 11“Nítorí náà èmi dámọ̀ràn pé, kí gbogbo Israẹli wọ́jọ pọ̀ sọ́dọ̀ rẹ, láti Dani títí dé Beerṣeba, gẹ́gẹ́ bí iyanrìn létí òkun fún ọ̀pọ̀lọpọ̀; àti pé, kí ìwọ tìkára rẹ̀ ó lọ sí ogun náà. 12Àwa ó sì yọ sí i níbikíbi tí àwa o gbé rí i, àwa ó sì yí i ká bí ìrì ti ń ṣẹ̀ sí ilẹ̀ àní, ọkàn kan kì yóò kù pẹ̀lú rẹ̀ nínú gbogbo àwọn ọmọkùnrin tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀. 13Bí o bá sì bọ́ sí ìlú kan, gbogbo Israẹli yóò mú okùn wá sí ìlú náà, àwa ó sì fà á lọ sí odò, títí a kì yóò fi rí òkúta kéékèèké kan níbẹ̀.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.