2 Samuẹli 16:8
2 Samuel 16:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Olúwa mú gbogbo ẹ̀jẹ̀ ìdílé Saulu padà wá sí orí rẹ, ní ipò ẹni tí ìwọ jẹ ọba; Olúwa ti fi ìjọba náà lé Absalomu ọmọ rẹ lọ́wọ́: sì wò ó, ìwà búburú rẹ ni ó mú èyí wá bá ọ, nítorí pé ọkùnrin ẹ̀jẹ̀ ni ìwọ.”
2 Samuel 16:8 in English
2 Samuel 16:8 · Berean Standard Bible
The LORD has paid you back for all the blood of the house of Saul, in whose place you have reigned, and the LORD has delivered the kingdom into the hand of your son Absalom. See, you have come to ruin because you are a man of bloodshed!”
Context
6Ó sì sọ òkúta sí Dafidi, àti sí gbogbo ìránṣẹ́ Dafidi ọba, àti sí gbogbo ènìyàn, gbogbo àwọn alágbára ọkùnrin sì wà lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti lọ́wọ́ òsì rẹ̀. 7Báyìí ni Ṣimei sì wí nígbà tí ó ń yọ èébú, “Jáde, ìwọ ọkùnrin ẹ̀jẹ̀, ìwọ ọkùnrin Beliali. 8Olúwa mú gbogbo ẹ̀jẹ̀ ìdílé Saulu padà wá sí orí rẹ, ní ipò ẹni tí ìwọ jẹ ọba; Olúwa ti fi ìjọba náà lé Absalomu ọmọ rẹ lọ́wọ́: sì wò ó, ìwà búburú rẹ ni ó mú èyí wá bá ọ, nítorí pé ọkùnrin ẹ̀jẹ̀ ni ìwọ.” 9Abiṣai ọmọ Seruiah sì wí fún ọba pé, “Èéṣe tí òkú ajá yìí fi ń bú olúwa mi ọba? Jẹ́ kí èmi kọjá, èmi bẹ̀ ọ́, kí èmi sì bẹ́ ẹ́ lórí.” 10Ọba sì wí pé, “Kín ni èmi ní ṣe pẹ̀lú yín, ẹ̀yin ọmọ Seruiah? Bí ó bá ń bú èébú, nítorí tí Olúwa ti wí fún un pé, ‘Bú Dafidi!’ Ta ni yóò sì wí pé, ‘Kín ni ìdí tí o fi ṣe bẹ́ẹ̀.’ ”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.