Native Bible

2 Samuel 16:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ọba, àti gbogbo àwọn ènìyàn tí ó ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ sì dé Jordani, ó sì rẹ̀ wọ́n, wọ́n sì sinmi níbẹ̀.

2 Samuel 16:14 in English

2 Samuel 16:14 · Berean Standard Bible

Finally, the king and all the people with him arrived,* exhausted. And there he refreshed himself.

Context

12Bóyá Ọlọ́run yóò wo ìpọ́njú mi, Olúwa yóò sì fi ìre san án fún mi ní ipò èébú rẹ̀ lónìí.” 13Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì ń lọ ní ọ̀nà, Ṣimei sì ń rìn òdìkejì òkè tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, ó sì ń yan èébú bí ó ti ń lọ, ó sì ń sọ ọ́ lókùúta, ó sì ń fọ́n erùpẹ̀. 14Ọba, àti gbogbo àwọn ènìyàn tí ó ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ sì dé Jordani, ó sì rẹ̀ wọ́n, wọ́n sì sinmi níbẹ̀. 15Absalomu àti gbogbo àwọn ènìyàn, àwọn ọkùnrin Israẹli sì wá sí Jerusalẹmu, Ahitofeli sì wà pẹ̀lú rẹ̀. 16Ó sì ṣe, nígbà tí Huṣai ará Arki, ọ̀rẹ́ Dafidi tọ Absalomu wá, Huṣai sì wí fún Absalomu pé, “Kí ọba ó pẹ́! Kí ọba ó pẹ́.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.