Native Bible

2 Samuel 15:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí tí ìránṣẹ́ rẹ ti jẹ́ ẹ̀jẹ́ kan nígbà tí èmi ń bẹ ní Geṣuri ní Siria pé, ‘Bí Olúwa bá mú mi padà wá sí Jerusalẹmu, nítòótọ́, èmi ó sì sin Olúwa.’ ”

2 Samuel 15:8 in English

2 Samuel 15:8 · Berean Standard Bible

For your servant made a vow while dwelling in Geshur of Aram, saying: ‘If indeed the LORD brings me back to Jerusalem, I will worship the LORD in Hebron.’*”

Context

6Irú ìwà báyìí ni Absalomu a máa hù sí gbogbo Israẹli tí ó tọ́ ọba wá nítorí ìdájọ́, Absalomu sì fi fa ọkàn àwọn ènìyàn Israẹli sọ́dọ̀ rẹ̀. 7Ó sì ṣe lẹ́yìn ogójì ọdún, Absalomu sì wí fún ọba pé, “Èmi bẹ́ ọ́, jẹ́ kí èmi ó lọ, kí èmi sì san ìlérí mi tí èmi ti ṣe fún Olúwa, ní Hebroni. 8Nítorí tí ìránṣẹ́ rẹ ti jẹ́ ẹ̀jẹ́ kan nígbà tí èmi ń bẹ ní Geṣuri ní Siria pé, ‘Bí Olúwa bá mú mi padà wá sí Jerusalẹmu, nítòótọ́, èmi ó sì sin Olúwa.’ ” 9Ọba sì wí fún un pé, “Máa lọ ní àlàáfíà.” Ó sì dìde, ó sì lọ sí Hebroni. 10Ṣùgbọ́n Absalomu rán àmì sáàrín gbogbo ẹ̀yà Israẹli pé, “Nígbà tí ẹ̀yin bá gbọ́ ìró ìpè, kí ẹ̀yin sì wí pé, ‘Absalomu jẹ ọba ní Hebroni.’ ”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.