2 Samuẹli 15:21
2 Samuel 15:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ittai sì dá ọba lóhùn, ó sì wí pé, “Bí Olúwa tí ń bẹ láààyè, àti bí olúwa mi ọba ti ń bẹ láààyè, nítòótọ́ níbikíbi tí olúwa mi ọba bá gbé wà, ìbá à ṣe nínú ikú, tàbí nínú ìyè, níbẹ̀ pẹ̀lú ni ìránṣẹ́ rẹ yóò gbé wà.”
2 Samuel 15:21 in English
2 Samuel 15:21 · Berean Standard Bible
But Ittai answered the king, “As surely as the LORD lives, and as my lord the king lives, wherever my lord the king may be, whether it means life or death, there will your servant be!”
Context
19Ọba sì wí fún Ittai ará Gitti pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ń bá wa lọ pẹ̀lú, padà, kí o sì ba ọba jókòó; nítorí pé àlejò ni ìwọ, ìwọ sì ti fi ìlú rẹ sílẹ̀. 20Lánàá yìí ni ìwọ dé, èmi ó ha sì mú kí ìwọ máa bá wá lọ káàkiri lónìí bí? Èmi ń lọ sí ibikíbi tí mo bá rí: padà, kí o sì mú àwọn arákùnrin rẹ padà, kí àánú àti òtítọ́ Olúwa wà pẹ̀lú rẹ.” 21Ittai sì dá ọba lóhùn, ó sì wí pé, “Bí Olúwa tí ń bẹ láààyè, àti bí olúwa mi ọba ti ń bẹ láààyè, nítòótọ́ níbikíbi tí olúwa mi ọba bá gbé wà, ìbá à ṣe nínú ikú, tàbí nínú ìyè, níbẹ̀ pẹ̀lú ni ìránṣẹ́ rẹ yóò gbé wà.” 22Dafidi sì wí fún Ittai pé, “Lọ kí o sì rékọjá!” Ittai ará Gitti náà sì rékọjá, àti gbogbo àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, àti gbogbo àwọn ọmọ kéékèèké tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀. 23Gbogbo ìlú náà sì fi ohùn rara sọkún, gbogbo ènìyàn sì rékọjá; ọba sì rékọjá àfonífojì Kidironi, gbogbo àwọn ènìyàn náà sì rékọjá, sí ìhà ọ̀nà ijù.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.