Native Bible

2 Samuel 15:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Dafidi sì wí fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ó wá lọ́dọ̀ rẹ̀ ni Jerusalẹmu pé, “Ẹ dìde! Ẹ jẹ́ kí a sálọ, nítorí pé kò sí ẹni tí yóò gbà wá lọ́wọ́ Absalomu; ẹ yára, kí a lọ kúrò, kí òun má bá à yára lé wa bá, kí ó má sì mú ibi bá wa, kí ó má sì fi ojú idà pa ìlú run.”

2 Samuel 15:14 in English

2 Samuel 15:14 · Berean Standard Bible

And David said to all the servants with him in Jerusalem, “Arise and let us flee, or we will not escape from Absalom! We must leave quickly, or he will soon overtake us, heap disaster on us, and put the city to the sword.”

Context

12Absalomu sì ránṣẹ́ pe Ahitofeli ará Giloni, ìgbìmọ̀ Dafidi, láti ìlú rẹ̀ wá, àní láti Giloni, nígbà tí ó ń rú ẹbọ. Ìdìmọ̀lù náà sì le; àwọn ènìyàn sì ń pọ̀ sọ́dọ̀ Absalomu. 13Ẹnìkan sì wá rò fún Dafidi pé, “Ọkàn àwọn ọkùnrin Israẹli ṣí sí Absalomu.” 14Dafidi sì wí fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ó wá lọ́dọ̀ rẹ̀ ni Jerusalẹmu pé, “Ẹ dìde! Ẹ jẹ́ kí a sálọ, nítorí pé kò sí ẹni tí yóò gbà wá lọ́wọ́ Absalomu; ẹ yára, kí a lọ kúrò, kí òun má bá à yára lé wa bá, kí ó má sì mú ibi bá wa, kí ó má sì fi ojú idà pa ìlú run.” 15Àwọn ìránṣẹ́ ọba sì wí fún ọba pé, “Gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí olúwa wa ọba ń fẹ́, wò ó, àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ ti murá.” 16Ọba sì jáde, gbogbo ilé rẹ̀ sì tẹ̀lé e. Ọba sì fì mẹ́wàá nínú àwọn obìnrin rẹ̀ sílẹ̀ láti máa ṣọ́ ilé.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.