2 Samuẹli 15:11
2 Samuel 15:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Igba ọkùnrin sì bá Absalomu ti Jerusalẹmu jáde, nínú àwọn tí a ti pè; wọ́n sì lọ nínú àìmọ̀kan wọn, wọn kò sì mọ nǹkan kan.
2 Samuel 15:11 in English
2 Samuel 15:11 · Berean Standard Bible
Two hundred men from Jerusalem accompanied Absalom. They had been invited as guests and they went along innocently, for they knew nothing about the matter.
Context
9Ọba sì wí fún un pé, “Máa lọ ní àlàáfíà.” Ó sì dìde, ó sì lọ sí Hebroni. 10Ṣùgbọ́n Absalomu rán àmì sáàrín gbogbo ẹ̀yà Israẹli pé, “Nígbà tí ẹ̀yin bá gbọ́ ìró ìpè, kí ẹ̀yin sì wí pé, ‘Absalomu jẹ ọba ní Hebroni.’ ” 11Igba ọkùnrin sì bá Absalomu ti Jerusalẹmu jáde, nínú àwọn tí a ti pè; wọ́n sì lọ nínú àìmọ̀kan wọn, wọn kò sì mọ nǹkan kan. 12Absalomu sì ránṣẹ́ pe Ahitofeli ará Giloni, ìgbìmọ̀ Dafidi, láti ìlú rẹ̀ wá, àní láti Giloni, nígbà tí ó ń rú ẹbọ. Ìdìmọ̀lù náà sì le; àwọn ènìyàn sì ń pọ̀ sọ́dọ̀ Absalomu. 13Ẹnìkan sì wá rò fún Dafidi pé, “Ọkàn àwọn ọkùnrin Israẹli ṣí sí Absalomu.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.