Native Bible

2 Samuel 14:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Obìnrin ará Tekoa náà sì wí fún ọba pé, “Olúwa mi, ọba, jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ náà wà lórí mi, àti lórí ìdílé baba mí; kí ọba àti ìtẹ́ rẹ̀ ó jẹ́ aláìlẹ́bi.”

2 Samuel 14:9 in English

2 Samuel 14:9 · Berean Standard Bible

But the woman of Tekoa said to the king, “My lord the king, may any blame be on me and on my father’s house, and may the king and his throne be guiltless.”

Context

7Sì wò ó, gbogbo ìdílé dìde sí ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀, wọ́n sì wí pé, ‘Fi ẹni tí ó pa arákùnrin rẹ fún wa, àwa ó sì pa á ní ipò ẹ̀mí arákùnrin rẹ̀ tí ó pa, àwa ó sì pa àrólé náà run pẹ̀lú.’ Wọn ó sì pa iná mi tí ó kù, wọn kì yóò sì fi orúkọ tàbí ẹni tí ó kú sílẹ̀ fún ọkọ mi ní ayé.” 8Ọba sì wí fún obìnrin náà pé, “Lọ sí ilé rẹ̀, èmi ó sì kìlọ̀ nítorí rẹ.” 9Obìnrin ará Tekoa náà sì wí fún ọba pé, “Olúwa mi, ọba, jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ náà wà lórí mi, àti lórí ìdílé baba mí; kí ọba àti ìtẹ́ rẹ̀ ó jẹ́ aláìlẹ́bi.” 10Ọba sì wí pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀ sí ọ, mú ẹni náà tọ̀ mí wá, òun kì yóò sì tọ́ ọ mọ́.” 11Ó sì wí pé, “Èmi bẹ̀ ọ́ jẹ́ kí ọba ó rántí Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, kí olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ má ṣe ní ipá láti ṣe ìparun, kí wọn o má bá a pa ọmọ mi!” Òun sì wí pé, “Bí Olúwa ti ń bẹ láààyè ọ̀kan nínú irun orí ọmọ rẹ ki yóò bọ sílẹ̀.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.