Native Bible

2 Samuel 14:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Joabu sì ránṣẹ́ sí Tekoa, ó sì mú ọlọ́gbọ́n obìnrin kan láti ibẹ̀ wá, ó sì wí fún un pé, “Èmi bẹ̀ ọ́, ṣe bí ẹni tí ń ṣọ̀fọ̀, kí o sì fi aṣọ ọ̀fọ̀ sára, kí o má sì ṣe fi òróró pa ara, kí o sì dàbí obìnrin ti ó ti ń ṣọ̀fọ̀ fún òkú lọ́jọ́ púpọ̀.

2 Samuel 14:2 in English

2 Samuel 14:2 · Berean Standard Bible

So Joab sent to Tekoa to bring a wise woman from there. He told her, “Please pretend to be a mourner; put on clothes for mourning and do not anoint yourself with oil. Act like a woman who has mourned for the dead a long time.

Context

1Joabu ọmọ Seruiah sì kíyèsi i, pé ọkàn ọba sì fà sí Absalomu. 2Joabu sì ránṣẹ́ sí Tekoa, ó sì mú ọlọ́gbọ́n obìnrin kan láti ibẹ̀ wá, ó sì wí fún un pé, “Èmi bẹ̀ ọ́, ṣe bí ẹni tí ń ṣọ̀fọ̀, kí o sì fi aṣọ ọ̀fọ̀ sára, kí o má sì ṣe fi òróró pa ara, kí o sì dàbí obìnrin ti ó ti ń ṣọ̀fọ̀ fún òkú lọ́jọ́ púpọ̀. 3Kí o sì tọ ọba wá, kí o sọ fún un gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ yìí.” Joabu sì fi ọ̀rọ̀ sí lẹ́nu. 4Nígbà tí obìnrin àrá Tekoa sì ń fẹ́ sọ̀rọ̀ fún ọba, ó wólẹ̀, ó dojúbolẹ̀, o sí bu ọlá fún un, o sì wí pé, “Ọba, gbà mi.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.