Native Bible

2 Samuel 14:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ọba sì wí pé, “Ọwọ́ Joabu kò ha wà pẹ̀lú rẹ nínú gbogbo èyí?” Obìnrin náà sì dáhùn ó sì wí pé, “Bí ẹ̀mí rẹ ti ń bẹ láààyè, olúwa mi ọba, kò sí ìyípadà sí ọwọ́ ọ̀tún, tàbí sí ọwọ́ òsì nínú gbogbo èyí tí olúwa mi ọba ti wí, nítorí pé Joabu ìránṣẹ́ rẹ, òun ni ó rán mi, òun ni ó sì fi gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí ìránṣẹ́bìnrin rẹ lẹ́nu.

2 Samuel 14:19 in English

2 Samuel 14:19 · Berean Standard Bible

So the king asked, “Is the hand of Joab behind all this?” The woman answered, “As surely as you live, my lord the king, no one can turn to the right or to the left from anything that my lord the king says. Yes, your servant Joab is the one who gave me orders; he told your maidservant exactly what to say.

Context

17“Ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ sì wí pé, ‘Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ ọba olúwa mi yóò sì jásí ìtùnú; nítorí bí angẹli Ọlọ́run bẹ́ẹ̀ ni olúwa mi ọba láti mọ rere àti búburú: Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò sì wà pẹ̀lú rẹ.’ ” 18Ọba sì dáhùn, ó sì wí fún obìnrin náà pé, “Má ṣe fi nǹkan tí èmi ó béèrè lọ́wọ́ rẹ pamọ́ fún mi, èmi bẹ̀ ọ́.” Obìnrin náà wí pé, “Jẹ́ kí olúwa mi ọba máa wí?” 19Ọba sì wí pé, “Ọwọ́ Joabu kò ha wà pẹ̀lú rẹ nínú gbogbo èyí?” Obìnrin náà sì dáhùn ó sì wí pé, “Bí ẹ̀mí rẹ ti ń bẹ láààyè, olúwa mi ọba, kò sí ìyípadà sí ọwọ́ ọ̀tún, tàbí sí ọwọ́ òsì nínú gbogbo èyí tí olúwa mi ọba ti wí, nítorí pé Joabu ìránṣẹ́ rẹ, òun ni ó rán mi, òun ni ó sì fi gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí ìránṣẹ́bìnrin rẹ lẹ́nu. 20Láti mú irú ọ̀rọ̀ wọ̀nyí wá ni Joabu ìránṣẹ́ rẹ ṣe ṣe nǹkan yìí: olúwa mi sì gbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ọgbọ́n angẹli Ọlọ́run, láti mọ gbogbo nǹkan tí ń bẹ̀ ní ayé.” 21Ọba sì wí fún Joabu pé, “Wò ó, èmi ó ṣe nǹkan yìí, nítorí náà lọ, kí o sì mú ọmọdékùnrin náà Absalomu padà wá.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.