Native Bible

2 Samuel 13:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Òun sì wí fún un pé, “Kó ha ní ìdí bí! Lílé tí ìwọ ń lé mi yìí burú ju èyí tí ìwọ ti ṣe sí mi lọ.” Ṣùgbọ́n òun kò fẹ́ gbọ́ tirẹ̀.

2 Samuel 13:16 in English

2 Samuel 13:16 · Berean Standard Bible

“No,” she replied, “sending me away is worse than this great wrong you have already done to me!” But he refused to listen to her.

Context

14Ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti gbọ́ ohùn rẹ̀; ó sì fi agbára mú un, ó sì ṣẹ́gun rẹ̀, ó sì bá a dàpọ̀. 15Amnoni sì kórìíra rẹ̀ gidigidi, ìríra náà sì wá ju ìfẹ́ tí òun ti ní sí i rí lọ. Amnoni sì wí fún un pé, “Dìde, kí o sì máa lọ!” 16Òun sì wí fún un pé, “Kó ha ní ìdí bí! Lílé tí ìwọ ń lé mi yìí burú ju èyí tí ìwọ ti ṣe sí mi lọ.” Ṣùgbọ́n òun kò fẹ́ gbọ́ tirẹ̀. 17Òun sì pe ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ tí í ṣe ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì wí fún un pé, “Jọ̀wọ́, ti obìnrin yìí sóde fún mi, kí o sì ti ìlẹ̀kùn mọ́ ọn.” 18Òun sì ní aṣọ aláràbarà kan lára rẹ̀, nítorí irú aṣọ àwọ̀lékè bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọbìnrin ọba tí í ṣe wúńdíá máa ń wọ̀. Ìránṣẹ́ rẹ̀ sì mú un jáde, ó sì ti ìlẹ̀kùn mọ́ ọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.