Native Bible

2 Samuel 12:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Dafidi sì dìde ní ilẹ̀, ó sì wẹ̀, ó fi òróró pa ara, ó sì pààrọ̀ aṣọ rẹ̀, ó sì wọ inú ilé Olúwa lọ, ó sì wólẹ̀ sin, ó sì wá sí ilé rẹ̀ ó sì béèrè, wọ́n sì gbé oúnjẹ kalẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì jẹun.

2 Samuel 12:20 in English

2 Samuel 12:20 · Berean Standard Bible

Then David got up from the ground, washed and anointed himself, changed his clothes, and went into the house of the LORD and worshiped. Then he went to his own house, and at his request they set food before him, and he ate.

Context

18Ní ọjọ́ keje, ọmọ náà sì kú. Àwọn ìránṣẹ́ Dafidi sì bẹ̀rù láti wí fún un pé, ọmọ náà kú: nítorí tí wọ́n wí pé, “Kíyèsi i, nígbà tí ọmọ náà ń bẹ láààyè, àwa sọ̀rọ̀ fún un, òun kọ̀ si gbọ́ ohùn wa! Ǹjẹ́ yóò ti ṣe ara rẹ̀ ní èṣe tó, bí àwa bá wí fún un pé, ọmọ náà kú.” 19Nígbà tí Dafidi sì rí pé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ń sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, Dafidi sì kíyèsi i, pé ọmọ náà kú, Dafidi sì béèrè lọ́wọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ọmọ náà kú bí?” Wọ́n sì dá a lóhùn pé, “Ó kú.” 20Dafidi sì dìde ní ilẹ̀, ó sì wẹ̀, ó fi òróró pa ara, ó sì pààrọ̀ aṣọ rẹ̀, ó sì wọ inú ilé Olúwa lọ, ó sì wólẹ̀ sin, ó sì wá sí ilé rẹ̀ ó sì béèrè, wọ́n sì gbé oúnjẹ kalẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì jẹun. 21Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì bí léèrè pé, “Kí ni èyí tí ìwọ ṣe yìí? Nítorí ọmọ náà nígbà tí ó ń bẹ láààyè ìwọ gbààwẹ̀, o sì sọkún; ṣùgbọ́n nígbà tí ọmọ náà kú, ó dìde ó sì jẹun.” 22Ó sì wí pé, “Nígbà tí ọmọ náà ń bẹ láààyè, èmi gbààwẹ̀, èmi sì sọkún: nítorí tí èmi wí pé, ‘Ta ni ó mọ̀? Bí Olúwa ó ṣàánú mi, kí ọmọ náà le yè.’

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.