2 Samuẹli 10:9
2 Samuel 10:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí Joabu sì rí i pé ogun náà dojúkọ òun níwájú àti lẹ́yìn, ó sì yàn nínú gbogbo àwọn akíkanjú ọkùnrin ní Israẹli, ó sì tẹ́ ogun kọjú sí àwọn ará Siria.
2 Samuel 10:9 in English
2 Samuel 10:9 · Berean Standard Bible
When Joab saw the battle lines before him and behind him, he selected some of the best men of Israel and arrayed them against the Arameans.
Context
7Dafidi sì gbọ́, ó sì rán Joabu, àti gbogbo ogún àwọn ọkùnrin alágbára. 8Àwọn ọmọ Ammoni sì jáde wá, wọ́n sì tẹ́ ogun ní ẹnu odi; ará Siria-Soba, àti ti Rehobu, àti Tobu, àti Maaka, wọ́n sì tẹ ogun ni pápá fún ara wọn. 9Nígbà tí Joabu sì rí i pé ogun náà dojúkọ òun níwájú àti lẹ́yìn, ó sì yàn nínú gbogbo àwọn akíkanjú ọkùnrin ní Israẹli, ó sì tẹ́ ogun kọjú sí àwọn ará Siria. 10Ó sì fi àwọn ènìyàn tí ó kù lé Abiṣai àbúrò rẹ̀ lọ́wọ́, kí ó lè tẹ ogun kọjú sí àwọn ọmọ Ammoni. 11Ó sì wí pé, “Bí agbára àwọn ará Siria bá pọ̀ ju èmi lọ, ìwọ yóò sì wá ràn mí lọ́wọ́, ṣùgbọ́n bí ọwọ́ àwọn ọmọ Ammoni bá sì pọ̀jù ọ́ lọ, èmi ó sì wá ràn ọ́ lọ́wọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.