Native Bible

2 Samuel 10:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wọ́n sì sọ fún Dafidi, ó sì ránṣẹ́ lọ pàdé wọn, nítorí tí ojú ti àwọn ọkùnrin náà púpọ̀: ọba sì wí pé, “Ẹ dúró ní Jeriko títí irùngbọ̀n yín yóò fi hù, nígbà náà ni kí ẹ tó máa bọ̀.”

2 Samuel 10:5 in English

2 Samuel 10:5 · Berean Standard Bible

When this was reported to David, he sent messengers to meet the men, since they had been thoroughly humiliated. The king told them, “Stay in Jericho until your beards have grown back, and then return.”

Context

3Àwọn olórí àwọn ọmọ Ammoni sì wí fún Hanuni olúwa wọn pé, “Ǹjẹ́ o rò pé Dafidi ń bu ọlá fún baba rẹ nígbà tí ó rán ènìyàn wá láti bá ọ kẹ́dùn? Kò ha ṣe pé Dafidi rán àwọn ìránṣẹ́ sí ọ láti wo ìlú àti láti yọ́ ọ wò àti láti gbà ọ́.” 4Hanuni sì mú àwọn ìránṣẹ́ Dafidi ó fá apá kan irùngbọ̀n wọn, ó sì gé ààbọ̀ kúrò ní agbádá wọn, títí ó fi dé ìdí wọn, ó sì rán wọn lọ. 5Wọ́n sì sọ fún Dafidi, ó sì ránṣẹ́ lọ pàdé wọn, nítorí tí ojú ti àwọn ọkùnrin náà púpọ̀: ọba sì wí pé, “Ẹ dúró ní Jeriko títí irùngbọ̀n yín yóò fi hù, nígbà náà ni kí ẹ tó máa bọ̀.” 6Àwọn ará Ammoni sì ri pé, wọ́n di ẹni ìríra níwájú Dafidi, àwọn ọmọ Ammoni sì ránṣẹ́, wọ́n sì fi owó bẹ́ ogún àwọn ará Siria ti Beti-Rehobu; àti Siria-Soba, ogún ẹgbẹ̀rún (20,000) ẹlẹ́ṣẹ̀ àti ti ọba Maaka, ẹgbẹ̀rún (1,000) ọkùnrin àti ti Tobu ẹgbàá mẹ́fà (12,000) ọkùnrin lọ́wẹ̀. 7Dafidi sì gbọ́, ó sì rán Joabu, àti gbogbo ogún àwọn ọkùnrin alágbára.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.