Native Bible

2 Samuel 10:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí àwọn ará Siria sì rí i pé àwọn ṣubú níwájú Israẹli, wọ́n sì kó ara wọn jọ

2 Samuel 10:15 in English

2 Samuel 10:15 · Berean Standard Bible

When the Arameans saw that they had been defeated by Israel, they regrouped.

Context

13Joabu àti àwọn ènìyàn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ sì bá àwọn ará Siria pàdé ìjà, wọ́n sì sá níwájú rẹ̀. 14Nígbà tí àwọn ọmọ Ammoni sì rí i pé àwọn ará Siria sá, àwọn pẹ̀lú sì sá níwájú Abiṣai, wọ́n sì wọ inú ìlú lọ. Joabu sì padà kúrò lẹ́yìn àwọn ọmọ Ammoni, ó sì wá sí Jerusalẹmu. 15Nígbà tí àwọn ará Siria sì rí i pé àwọn ṣubú níwájú Israẹli, wọ́n sì kó ara wọn jọ 16Hadadeseri sì ránṣẹ́, ó sì mú àwọn Siria tí ó wà ní òkè odò Eufurate jáde wá, wọ́n sì wá sí Helami; Sobaki olórí ogun Hadadeseri sì ṣe olórí wọn. 17Nígbà tí a sọ fún Dafidi, ó sì kó gbogbo Israẹli jọ, wọ́n sì kọjá Jordani, wọ́n sì wá sí Helami, àwọn ará Siria sì tẹ́ ogun kọjú sí Dafidi, wọ́n sì bá a jà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.