Native Bible

2 Samuel 1:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní ọjọ́ kẹta, ọkùnrin kan dé láti ibi ibùdó Saulu, pẹ̀lú aṣọ rẹ̀ tí ó ti ya; àti erùpẹ̀ ní orí rẹ̀. Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ Dafidi, ó wólẹ̀ fún un láti bu ọlá fún un.

2 Samuel 1:2 in English

2 Samuel 1:2 · Berean Standard Bible

On the third day a man with torn clothes and dust on his head arrived from Saul’s camp. When he came to David, he fell to the ground to pay him homage.

Context

1Lẹ́yìn ikú Saulu, Dafidi ti ibi tí ó ti ṣẹ́gun àwọn ará Amaleki bọ̀, ó sì dúró ní Siklagi ní ọjọ́ méjì. 2Ní ọjọ́ kẹta, ọkùnrin kan dé láti ibi ibùdó Saulu, pẹ̀lú aṣọ rẹ̀ tí ó ti ya; àti erùpẹ̀ ní orí rẹ̀. Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ Dafidi, ó wólẹ̀ fún un láti bu ọlá fún un. 3Dafidi sì béèrè pé, “Ibo ni ìwọ ti wá?” “Èmi sá láti ibùdó àwọn ọmọ Israẹli.” 4Dafidi béèrè pé, “Kí ni ó ṣẹlẹ̀?” “Sọ fún mi.” Ó wí pé, “Àwọn ọkùnrin náà sá láti ojú ogun. Ọ̀pọ̀ wọn ṣubú, wọ́n sì kú. Saulu àti ọmọ rẹ̀ ọkùnrin Jonatani sì kú pẹ̀lú.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.