2 Samuẹli 1:11
2 Samuel 1:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà ni, Dafidi àti gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, di aṣọ wọn mú, wọ́n sì fà á ya.
2 Samuel 1:11 in English
2 Samuel 1:11 · Berean Standard Bible
Then David took hold of his own clothes and tore them, and all the men who were with him did the same.
Context
9“Nígbà náà ó wí fún mi pé, ‘Dúró lórí ì mi kí o sì pa mí! Èmi wà nínú ìrora ikú, ṣùgbọ́n mo wà láààyè.’ 10“Nígbà náà, mo dúró lórí i rẹ̀, mo sì pa á nítorí mo mọ̀ wí pé, lẹ́yìn ìgbà tí ó ti ṣubú, kò le è yè mọ́. Mo sì mú adé tí ó wà lórí rẹ̀, idẹ tí ó wà ní apá a rẹ̀, mo sì kó wọn wá síbí fún olúwa mi.” 11Nígbà náà ni, Dafidi àti gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, di aṣọ wọn mú, wọ́n sì fà á ya. 12Wọ́n ṣọ̀fọ̀, wọ́n sì sọkún, wọ́n sì gbààwẹ̀ títí di ìrọ̀lẹ́ fún Saulu àti ọmọ rẹ̀ Jonatani àti fún àwọn ọmọ-ogun Olúwa, àti fún àwọn ilé Israẹli, nítorí wọ́n ti ṣubú nípa idà. 13Dafidi sọ fún ọkùnrin tí ó mú ìròyìn wá fún un pé, “Níbo ni ó ti wá?”
O dáhùn pé, “Ọmọ àlejò ni mo jẹ́, ará Amaleki.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.