2 Peteru 2:16
2 Peter 2:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n a bá a wí nítorí ìrékọjá rẹ̀, odi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ fi ohùn ènìyàn sọ̀rọ̀, ó sì fi òpin sí ìṣiwèrè wòlíì náà.
2 Peter 2:16 in English
2 Peter 2:16 · Berean Standard Bible
But he was rebuked for his transgression by a donkey, otherwise without speech, that spoke with a man’s voice and restrained the prophet’s madness.
Context
14Ojú wọn kún fún panṣágà, wọn kò sì dẹ́kun ẹ̀ṣẹ̀ dídá; wọ́n ń tan àwọn tí ọkàn kò fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ jẹ; àwọn tí wọ́n ní ọkàn tí ó ti yege nínú wọ̀bìà, ọmọ ègún ni wọ́n. 15Wọ́n kọ ọ̀nà tí ó tọ́ sílẹ̀, wọ́n sì ṣáko lọ, wọ́n tẹ̀lé ọ̀nà Balaamu ọmọ Beori, ẹni tó fẹ́ràn èrè àìṣòdodo. 16Ṣùgbọ́n a bá a wí nítorí ìrékọjá rẹ̀, odi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ fi ohùn ènìyàn sọ̀rọ̀, ó sì fi òpin sí ìṣiwèrè wòlíì náà. 17Àwọn wọ̀nyí ni kànga tí kò ní omi, ìkùùkuu tí ẹ̀fúùfù ń gbá kiri; àwọn ẹni tí a pa òkùnkùn biribiri mọ́ dè títí láé. 18Nítorí ìgbà tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ ìhàlẹ̀ asán, nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara, wọn a máa tan àwọn tí wọ́n fẹ́rẹ̀ má tí ì bọ́ tán kúrò lọ́wọ́ àwọn tí wọ́n wà nínú ìṣìnà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.