Native Bible

2 Peter 1:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwa sì ní ìfẹsẹ̀múlẹ̀ ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì dunjúdunjú sí i, èyí tí ó yẹ kí ẹ kíyèsi gẹ́gẹ́ bí fìtílà tó ń mọ́lẹ̀ níbi tí òkùnkùn gbé wà, títí ilẹ̀ yóò fi mọ́, tí ìràwọ̀ òwúrọ̀ yóò sì yọ lọ́kàn yín.

2 Peter 1:19 in English

2 Peter 1:19 · Berean Standard Bible

We also have the word of the prophets as confirmed beyond doubt. And you will do well to pay attention to it, as to a lamp shining in a dark place, until the day dawns and the morning star rises in your hearts.

Context

17Nítorí tí Ó gba ọlá àti ògo láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba, nígbà tí irú ohùn yìí fọ̀ sí i láti inú ògo ńlá náà wá pé, “Èyí ni àyànfẹ́ ọmọ mi, ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi.” 18Àwa pẹ̀lú sì gbọ́ ohun yìí tí ó ti ọ̀run wá nígbà tí àwa wà pẹ̀lú rẹ̀ ní orí òkè mímọ́ náà. 19Àwa sì ní ìfẹsẹ̀múlẹ̀ ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì dunjúdunjú sí i, èyí tí ó yẹ kí ẹ kíyèsi gẹ́gẹ́ bí fìtílà tó ń mọ́lẹ̀ níbi tí òkùnkùn gbé wà, títí ilẹ̀ yóò fi mọ́, tí ìràwọ̀ òwúrọ̀ yóò sì yọ lọ́kàn yín. 20Ju gbogbo rẹ̀ lọ, kí ẹ ní òye yìí pé kò sí àsọtẹ́lẹ̀ ìwé mímọ́ kankan tí ó wáyé nípa ìtumọ̀ wòlíì fún rara rẹ̀. 21Nítorí àsọtẹ́lẹ̀ kan kò ti ipá ìfẹ́ ènìyàn wá rí; ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ń sọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bí a ti ń darí wọn láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ wá.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.