Native Bible

2 Peter 1:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bí èmi ti mọ̀ pé, bíbọ́ àgọ́ ara mi yìí sílẹ̀ kù sí dẹ̀dẹ̀, àní, bí Olúwa wa Jesu Kristi ti fihàn mí.

2 Peter 1:14 in English

2 Peter 1:14 · Berean Standard Bible

because I know that this tent will soon be laid aside, as our Lord Jesus Christ has made clear to me.

Context

12Nítorí náà, èmi ó máa rán yin létí àwọn nǹkan wọ̀nyí nígbà gbogbo, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀yin ti mọ̀ wọ́n, tí ẹsẹ̀ yín sì múlẹ̀ nínú òtítọ́ tí ẹ ní báyìí. 13Èmi sì rò pé ó tọ́ láti máa mú wọn wá sí ìrántí yín, níwọ̀n ìgbà tí èmí ba ń bẹ nínú àgọ́ ara yìí. 14Bí èmi ti mọ̀ pé, bíbọ́ àgọ́ ara mi yìí sílẹ̀ kù sí dẹ̀dẹ̀, àní, bí Olúwa wa Jesu Kristi ti fihàn mí. 15Èmi ó sì máa ṣaápọn pẹ̀lú, kí ẹ̀yin lè máa rántí nǹkan wọ̀nyí nígbà gbogbo lẹ́yìn ikú mi. 16Nítorí kì í ṣe bí ẹni tí ó ń tọ ìtàn asán lẹ́yìn tí a fi ọgbọ́nkọ́gbọ́n là sílẹ̀, nígbà tí àwa sọ fún yín ní ti agbára àti wíwá Jesu Kristi Olúwa, ṣùgbọ́n ẹlẹ́rìí ọláńlá rẹ̀ ni àwa jẹ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.