2 Peteru 1:11
2 Peter 1:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí báyìí ni a ó pèsè fún yín lọ́pọ̀lọ́pọ̀ láti wọ ìjọba àìnípẹ̀kun ti Olúwa àti Olùgbàlà wa Jesu Kristi.
2 Peter 1:11 in English
2 Peter 1:11 · Berean Standard Bible
and you will receive a lavish reception into the eternal kingdom of our Lord and Savior Jesus Christ.
Context
9Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ṣe aláìní nǹkan wọ̀nyí, kò lè ríran ní òkèèrè, ó fọjú, ó sì ti gbàgbé pé a ti wẹ òun nù kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ àtijọ́. 10Nítorí náà, ará ẹ túbọ̀ máa ṣe àìsimi láti sọ ìpè àti yíyàn yín di dájúdájú, nítorí bí ẹ̀yin bá ń ṣe nǹkan wọ̀nyí, ẹ̀yin kì yóò ṣubú. 11Nítorí báyìí ni a ó pèsè fún yín lọ́pọ̀lọ́pọ̀ láti wọ ìjọba àìnípẹ̀kun ti Olúwa àti Olùgbàlà wa Jesu Kristi. 12Nítorí náà, èmi ó máa rán yin létí àwọn nǹkan wọ̀nyí nígbà gbogbo, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀yin ti mọ̀ wọ́n, tí ẹsẹ̀ yín sì múlẹ̀ nínú òtítọ́ tí ẹ ní báyìí. 13Èmi sì rò pé ó tọ́ láti máa mú wọn wá sí ìrántí yín, níwọ̀n ìgbà tí èmí ba ń bẹ nínú àgọ́ ara yìí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.