Native Bible

2 Kings 9:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bẹ́ẹ̀ ni, ọba rán ọkùnrin ẹlẹ́ṣin kejì. Nígbà náà ó wá sí ọ̀dọ̀ wọn, ó wí pé, “Èyí ni ohun tí ọba sọ: “Ṣé ìwọ wá pẹ̀lú àlàáfíà?” Jehu dáhùn, “Dúró sí ẹ̀yìn mi.”

2 Kings 9:19 in English

2 Kings 9:19 · Berean Standard Bible

So the king sent out a second horseman, who went to them and said, “This is what the king asks: ‘Have you come in peace?’” “What do you know about peace?” Jehu replied. “Fall in behind me.”

Context

17Nígbà tí olùṣọ́ kan tí ó dúró ní ilé ìṣọ́ ní Jesreeli, rí ọ̀wọ́ ogun Jehu tí wọ́n ń súnmọ́ tòsí, ó pè jáde, “Mo rí àwọn ọ̀wọ́ ogun tí ó ń bọ̀.” “Mú ọkùnrin ẹlẹ́ṣin kan,” Joramu pa á láṣẹ. “Rán an lọ sí ọ̀dọ̀ wọn kí o sì béèrè pé, ‘Ṣé ẹ̀yin wá pẹ̀lú àlàáfíà?’ ” 18Ọkùnrin ẹlẹ́ṣin náà, lọ láti lọ bá Jehu ó sì wí pé, “Èyí ni ohun tí ọba wí: ‘Ṣé ìwọ wá pẹ̀lú àlàáfíà?’ ” “Kí ni ìwọ ní ṣe pẹ̀lú àlàáfíà?” Jehu sì dáhùn. “Bọ́ sí ẹ̀yìn mi.” Olùṣọ́ náà sì wí fún un pé, “Ìránṣẹ́ náà ti dé ọ̀dọ̀ wọn, ṣùgbọ́n kò tún padà wá mọ́.” 19Bẹ́ẹ̀ ni, ọba rán ọkùnrin ẹlẹ́ṣin kejì. Nígbà náà ó wá sí ọ̀dọ̀ wọn, ó wí pé, “Èyí ni ohun tí ọba sọ: “Ṣé ìwọ wá pẹ̀lú àlàáfíà?” Jehu dáhùn, “Dúró sí ẹ̀yìn mi.” 20Olùṣọ́ náà sì fi sùn. “Ó ti dé ọ̀dọ̀ wọn, ṣùgbọ́n kò tún padà wá mọ́ pẹ̀lú. Wíwá rẹ̀ sì dàbí ti Jehu ọmọ Nimṣi, ó ń wa kẹ̀kẹ́ bí ti aṣiwèrè.” 21“Fi ìwọ̀ kọ́ kẹ̀kẹ́ ogun mi.” Joramu pa á láṣẹ. Àti nígbà tí a fi kọ́, Joramu ọba Israẹli àti Ahasiah ọba Juda, gun kẹ̀kẹ́ lọ, olúkúlùkù nínú kẹ̀kẹ́ ogun tirẹ̀, láti lọ bá Jehu. Wọ́n bá a pàdé ní ibi oko tí ó ti jẹ́ ti Naboti ará Jesreeli.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.