Native Bible

2 Kings 9:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wọ́n ṣe gírí, wọ́n sì mú agbádá a wọn, wọ́n sì tàn wọ́n sí abẹ́ rẹ̀ ní orí àtẹ̀gùn. Nígbà náà, wọ́n fọn ìpè, wọ́n sì kígbe, “Jehu jẹ ọba!”

2 Kings 9:13 in English

2 Kings 9:13 · Berean Standard Bible

Quickly, each man took his garment and put it under Jehu on the bare steps. Then they blew the ram’s horn and proclaimed, “Jehu is king!”

Context

11Nígbà tí Jehu jáde lọ bá àwọn ọgbà ìjòyè e rẹ̀, ọ̀kan nínú wọn sì bi í pé, “Ṣé gbogbo nǹkan dára?” Kí ni ó dé tí aṣiwèrè fi tọ̀ ọ́ wá, “Ìwọ mọ ọkùnrin náà àti irú nǹkan tí ó ń sọ,” Jehu fèsì. 12“Ìyẹn kì í ṣe òótọ́!” Wọ́n wí. “Sọ fún wa.” Jehu wí, “Èyí ni ohun tí ó sọ fún mi: ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí, “Èmi fi àmì òróró yàn ọ́ ní ọba lórí Israẹli.” ’ ” 13Wọ́n ṣe gírí, wọ́n sì mú agbádá a wọn, wọ́n sì tàn wọ́n sí abẹ́ rẹ̀ ní orí àtẹ̀gùn. Nígbà náà, wọ́n fọn ìpè, wọ́n sì kígbe, “Jehu jẹ ọba!” 14Bẹ́ẹ̀ ni Jehu ọmọ Jehoṣafati, ọmọ Nimṣi, dìtẹ̀ sí Joramu. (Nísinsin yìí Joramu àti gbogbo Israẹli ti ń dáàbò bo Ramoti Gileadi nítorí Hasaeli ọba Aramu. 15ṣùgbọ́n ọba Joramu ti padà sí Jesreeli láti lọ sàn nínú ọgbẹ́ tí àwọn ará Aramu ti dá sí i lára nínú ogun pẹ̀lú ọba Hasaeli ti Aramu.) Jehu wí pé, “Tí èyí bá jẹ́ ọ̀nà tí ò ń rò, má ṣe jẹ́ kí ẹnìkankan kí ó yọ jáde nínú ìlú ńlá láti lọ sọ ìròyìn náà ní Jesreeli.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.