2 Ọba 8:6
2 Kings 8:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọba béèrè lọ́wọ́ obìnrin náà nípa rẹ̀, ó sì sọ fún un. Ó sì yan ìjòyè kan fún ún fún ọ̀rọ̀ rẹ̀ ó sì wí fún un pé, “Ẹ fún un padà gbogbo ohun tí ó bá jẹ́ tirẹ̀, àti pẹ̀lú gbogbo èrè ilé rẹ̀ fún ún láti ọjọ́ tí ó ti kúrò ní ìlú títí di àsìkò yìí.”
2 Kings 8:6 in English
2 Kings 8:6 · Berean Standard Bible
When the king asked the woman, she confirmed it. So the king appointed for her an officer, saying, “Restore all that was hers, along with all the proceeds of the field from the day that she left the country until now.”
Context
4Ọba sì ń sọ̀rọ̀ sí Gehasi, ìránṣẹ́ ènìyàn Ọlọ́run pé, “Sọ fún mi nípa gbogbo ohun ńlá tí Eliṣa ti ṣe.” 5Bí Gehasi ti ń sọ bí tí Eliṣa ṣe jí òkú di alààyè, obìnrin náà tí ọmọ rẹ̀ ọkùnrin tí Eliṣa ti dá padà sí ayé wá láti bẹ ọba fún ilé àti ilẹ̀ rẹ̀.
Gehasi sì wí pé, “Obìnrin náà nìyìí olúwa mi ọba, ọmọkùnrin rẹ náà nìyí tí Eliṣa ti jí dìde sí ayé.” 6Ọba béèrè lọ́wọ́ obìnrin náà nípa rẹ̀, ó sì sọ fún un.
Ó sì yan ìjòyè kan fún ún fún ọ̀rọ̀ rẹ̀ ó sì wí fún un pé, “Ẹ fún un padà gbogbo ohun tí ó bá jẹ́ tirẹ̀, àti pẹ̀lú gbogbo èrè ilé rẹ̀ fún ún láti ọjọ́ tí ó ti kúrò ní ìlú títí di àsìkò yìí.” 7Eliṣa lọ sí Damasku, Beni-Hadadi ọba Siria ń ṣe àìsàn. Nígbà tí wọ́n sọ fún ọba pé, “Ènìyàn Ọlọ́run ti wá láti gbogbo ọ̀nà òkè síbí,” 8ọba sì wí fún Hasaeli pé, “Mú ọrẹ lọ́wọ́ rẹ, sì lọ pàdé ènìyàn Ọlọ́run. Kí o sì béèrè Olúwa láti ọ̀dọ̀ rẹ̀, béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé ṣé èmi yóò sàn nínú àìsàn yìí?”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.