Native Bible

2 Kings 7:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí àwọn ọkùnrin tí ó ní ààrùn ẹ̀tẹ̀ dé ẹ̀gbẹ́ ibùdó wọ́n sì wọ inú ọ̀kan nínú àgọ́ náà. Wọ́n jẹ wọ́n sì mu, wọ́n sì kó fàdákà, wúrà àti ẹ̀wù, wọ́n sì lọ. Wọ́n sì wọ àgọ́ mìíràn lọ, wọ́n kó àwọn nǹkan láti ibẹ̀ wọ́n sì kó wọn pamọ́ pẹ̀lú.

2 Kings 7:8 in English

2 Kings 7:8 · Berean Standard Bible

When the lepers reached the edge of the camp, they went into a tent to eat and drink. Then they carried off the silver, gold, and clothing, and went and hid them. On returning, they entered another tent, carried off some items from there, and hid them.

Context

6nítorí tí Olúwa jẹ́ kí àwọn ará Siria gbọ́ ìró kẹ̀kẹ́ àti ẹṣin àti ogun ńlá, wọ́n sì wí fún ara wọn pé, “Ẹ wò ó, ọba Israẹli ti bẹ ogun àwọn Hiti àti àwọn ọba Ejibiti láti dojúkọ wá!” 7Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì dìde wọ́n sì sálọ ní àfẹ̀mọ́júmọ́ wọ́n sì fi àgọ́ wọn sílẹ̀ àti ẹṣin wọn àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Wọ́n sì fi ibùdó sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti wà, wọ́n sì sálọ fún ẹ̀mí wọn. 8Nígbà tí àwọn ọkùnrin tí ó ní ààrùn ẹ̀tẹ̀ dé ẹ̀gbẹ́ ibùdó wọ́n sì wọ inú ọ̀kan nínú àgọ́ náà. Wọ́n jẹ wọ́n sì mu, wọ́n sì kó fàdákà, wúrà àti ẹ̀wù, wọ́n sì lọ. Wọ́n sì wọ àgọ́ mìíràn lọ, wọ́n kó àwọn nǹkan láti ibẹ̀ wọ́n sì kó wọn pamọ́ pẹ̀lú. 9Nígbà náà wọ́n wí fún ara wọn pé, “Àwa kò ṣe ohun rere. Òní yìí jẹ́ ọjọ́ ìròyìn rere àwa sì pa á mọ́ ara wa. Tí àwa bá dúró títí di àfẹ̀mọ́júmọ́, ìjìyà yóò jẹ́ ti wa. Ẹ jẹ́ kí a lọ ní ẹ̀ẹ̀kan kí a lọ ròyìn èyí fún àwọn ilé ọba.” 10Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì lọ wọ́n sì pe àwọn asọ́bodè ìlú, wọ́n sì wí fún wọn pé, “Àwa lọ sí ibùdó àwọn ará Siria kò sì sí ọkùnrin kankan níbẹ̀ tàbí ohùn ènìyàn kan àyàfi ẹṣin tí a so àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àwọn àgọ́ náà sì wà gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti wà.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.