2 Ọba 7:15
2 Kings 7:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọ́n sì tẹ̀lé wọn títí dé Jordani, wọ́n sì rí gbogbo ọ̀nà kún fún agbádá pẹ̀lú ohun èlò tí ará àwọn Siria gbé sọnù ní yàrá wọn. Ìránṣẹ́ náà padà ó sì wá sọ fún ọba.
2 Kings 7:15 in English
2 Kings 7:15 · Berean Standard Bible
And they tracked them as far as the Jordan, and indeed, the whole way was littered with the clothing and equipment the Arameans had thrown off in haste. So the scouts returned and told the king.
Context
13Ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ dáhùn pé, “Èmí o bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí àwa kí ó mú márùn-ún nínú àwọn ẹṣin tí ó kù, nínú àwọn tí ó kù ní ìlú—kíyèsí i, wọ́n sá dàbí gbogbo àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ Israẹli tí ó kù nínú rẹ̀, kíyèsí i, àní bí gbogbo ènìyàn Israẹli tí a run, sí jẹ́ kí a rán wọn lọ láti lọ wo ohun tí ó ṣẹlẹ̀.” 14Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n yan kẹ̀kẹ́ méjì pẹ̀lú ẹṣin wọn, ọba sì ránṣẹ́ tọ ogun àwọn ará Siria lẹ́yìn ó pàṣẹ fún àwọn awakọ̀ pé, “Ẹ lọ kí ẹ lọ wo ohun tí ó ṣẹlẹ̀.” 15Wọ́n sì tẹ̀lé wọn títí dé Jordani, wọ́n sì rí gbogbo ọ̀nà kún fún agbádá pẹ̀lú ohun èlò tí ará àwọn Siria gbé sọnù ní yàrá wọn. Ìránṣẹ́ náà padà ó sì wá sọ fún ọba. 16Nígbà náà àwọn ènìyàn jáde lọ ìkógun ní ibùdó àwọn ará Siria. Bẹ́ẹ̀ ni òsùwọ̀n ìyẹ̀fun kan ni wọ́n tà fún ṣékélì kan, àti òsùwọ̀n barle méjì ní ṣékélì kan, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ. 17Nísinsin yìí ọba sì mú ìjòyè náà lórí ẹni tí ó fi ọwọ́ ara rẹ̀ tì ní ìkáwọ́ ẹnu ibodè, àwọn ènìyàn sì tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ ní ẹnu ibodè. Ó sì kú, gẹ́gẹ́ bí ènìyàn Ọlọ́run ti sọtẹ́lẹ̀ nígbà tí ọba sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.