Native Bible

2 Kings 6:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Eliṣa sọ fún wọn pé, “Èyí kì í ṣe ọ̀nà bẹ́ẹ̀ ni èyí kì í ṣe ìlú náà. Tẹ̀lé mi, èmi yóò mú u yín lọ sí ọ̀dọ̀ ọkùnrin tí ẹ̀yin ń wá.” Ó sì sìn wọ́n lọ sí Samaria.

2 Kings 6:19 in English

2 Kings 6:19 · Berean Standard Bible

And Elisha told them, “This is not the way, and this is not the city. Follow me, and I will take you to the man you are seeking.” And he led them to Samaria.

Context

17Eliṣa sì gbàdúrà, “Olúwa, la ojú rẹ̀ kí ó ba à lè ríran.” Nígbà náà Olúwa la ojú ìránṣẹ́ náà, ó sì wò, ó sì rí òkè ńlá tí ó kún fún ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ iná gbogbo yí Eliṣa ká. 18Bí àwọn ọ̀tá ṣe ń sọ̀kalẹ̀ wá níwájú rẹ, Eliṣa gbàdúrà sí Olúwa pé. “Bu ìfọ́jú lu àwọn ènìyàn wọ̀nyí,” Olúwa sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Eliṣa ti béèrè. 19Eliṣa sọ fún wọn pé, “Èyí kì í ṣe ọ̀nà bẹ́ẹ̀ ni èyí kì í ṣe ìlú náà. Tẹ̀lé mi, èmi yóò mú u yín lọ sí ọ̀dọ̀ ọkùnrin tí ẹ̀yin ń wá.” Ó sì sìn wọ́n lọ sí Samaria. 20Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n wọ ìlú náà, Eliṣa wí pé, “Olúwa, la ojú àwọn ọkùnrin wọ̀nyí kí wọn kí ó lè ríran.” Nígbà náà Olúwa la ojú wọn, wọ́n sì ríran, wọ́n sì wà níbẹ̀, nínú Samaria. 21Nígbà tí ọba Israẹli rí wọn, ó béèrè lọ́wọ́ Eliṣa pé, “Ṣé kí èmi kí ó pa wọ́n, baba mi? Ṣé kí èmi kí ó pa wọ́n?”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.